Super Eagles: Iwobi ati agbabọọlu mẹtala mii wọ Poland

Ikọ agbabọọlu Super Eagles n ya fọto saaju ifẹsẹwọnsẹ kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Agbabọọlu mẹrinla lo ti gunlẹ si ibudo igbaradi naa

Ibudo igbaradi fun ikọ agbabọọlu Super Eagles lati koju akẹgbẹ rẹ lati orilẹede Poland ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ti yoo waye lọjọ ẹti ti bẹrẹ si nii kun bayii.

Agbabọọlu ikọ Arsenal, Alex Iwobi lo lewaju awọn agbabọọlu to kọkọ gunlẹ si ibudo naa lọjọ aje.

Awọn agbabọọlu to sẹsẹ darapọ mọ wọn nibẹ ni Francis Uzoho, Elderson Echiejile, Stephen Eze, Joel Obi, Shehu Abdullahi, John Ogu, Moses Simon, pẹlu Kenneth Omeruo.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọn si n reti balogun ikọ Super Eagles, Mikel Obi

Awọn agbabọọlu ti wọn ti gunlẹ sibẹ saaju ni Troost Ekong, Ola Aina, Tyronne Ebuehi, Brian Idowu ati Leon Balogun.

Lowurọ ọjọ isẹgun lawọn agbabọọlu mẹjọ darapọ mọ awọn mẹfa to ti wa nilẹ bayii ni ibudo igbaradi naa.

Awọn agbabọọlu mejidinlọgbọn ti wọn n gbabọọlu jẹun lorilẹede Naijiria ati nilẹ okeere ni olukọni ikọ naa, Gernot Rohr ransẹ pe lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ meji ọtọọtọ ti yoo waye lọjọ ẹti laarin orilẹede Naijiria ati Poland pẹlu eleyi ti yoo waye laarin orilẹede Naijiria ati Serbia nilu London.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọ agbabọọlu Super eagles yoo maa koju Poland and Serbia gẹgẹbii ara igbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye

Ikọ agbabọọlu Super eagles yoo maa koju Poland gẹgẹbii ara igbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye losu kẹfa ọdun 2018 lorilẹede Russia.

Orilẹede Naijiria yoo maa koju Argentina, Croatia, Iceland ni ipele akọkọ idije naa.