Koko iroyin fun t'oni: Ikọlu BBC l'Eko, wahala Facebook
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti oni.
BBC ni ikọlu ni Olushosun/Ojota
Pẹlu Joshua Ajayi, BBC Yoruba, Lagos
Ijọba ipinlẹ Eko ti paṣẹ atipa ile idalẹnu Olushosun
Ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n risi eto aabo agbegbe ati ayika fi ipa gba ẹrọ alagbeka lọwọ mi ni Olushosun ni irọlẹ ọjọ aje nigbati wọn n ti ile-ilẹ naa.
Eefin ti nru jade lati agbegbe Olushosun/Ojota lati ọsẹ to kọja ti ogunlọgọ si ti n pariwo tantan lori ọrọ ilera won.
Ṣugbọn Kọmisọna fun eto agbegbe, ọgbẹni Babatunde Durosinmi-Etti ti tọrọ aforiji lọwọ ileeṣẹ BBC fun iwa ipanle yii. Fun ẹkunrẹrẹ, ẹ wo ibi itakun yii.
Ẹ wo oun ti awọn olutaja ni adugbo naa nsọ:
'Ijọba fẹ le wa kuro ni Ọjọta'
Facebook wọ gau lori aawọ data
Awọn oloṣelu ni orilẹede Amerika, Yuroopu ati Ilẹ Gẹẹsi ti kan si awọn alaṣẹ oju opo idọrẹ lori itakun agbaye, Facebook lati ṣalaye lori bi ileeṣẹ Cambridge Analytica ṣe ni akọọlẹ iroyin awọn eniyan lai gba aṣẹ latọdọ wọn.
Awọn Senatọ ni Amẹrika pe adari Facecook, Mark Zukerberg lati wa salaye nile igbimọ asofin lori ọna to maa gba lati daabo bo akọsilẹ iroyin awọn eniyan to wa lori Facebook.
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
Rasheed Tijani ni ipenija oju ṣugbọn ko jẹ k'o fa idiwọ fun oun lati ṣiṣẹ oojọ rẹ nibi ti o ti nlọ ata.
Ẹni ti ko riran to nlọ'ta ni Mushin