Ọlọta ti Ọta n lewaju fun ipamo aṣa ati iṣe Yoruba

Oba Abdulkabir Adeyemi Obalanlege ati Ooni ti Ile Ife Image copyright OLOTA OF OTA PALACE
Àkọlé àwòrán Ọlọta ti Ọta n lewaju fun ipamo aṣa ati iṣe Yoruba

Ọlọta ti Ọta, Ọba (Dr) Abdulkabir Adeyemi Obalanlege ti pe fun ki awọn ọba alaye lati rii daju wipe wọn pa aṣa ati iṣe Yoruba mọ.

Ọba tuntun ti ijọba ibilẹ Ado Odo/Ota ni ipinlẹ Ogun s'ọrọ yi nigba tio ṣe abẹwo si Ọọni ti Ile-Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi ni Ile Ife ni'pinlẹ Osun.

Image copyright OLOTA OF OTA PALACE
Àkọlé àwòrán Ọba Obalanlege npe fun ibọwọ fun aṣa ati iṣe Yoruba

Ninu atẹjade ti wọn fi sita lati ọwọ alukoro fun ọba naa, Seyi Oyetoro sọ wipe ọba naa pe fun iṣọkan awọn ọmọ Yoruba lati gbe aṣa ati iṣe ilẹ naa larugẹ.

Ọba Adeyeye Ogunwusi nigba to n fesi sọ wipe awọn ara Ota ṣan'wa lati ilu Ifẹ ni ọdun gbọgbọrọ sẹyin.

Image copyright OLOTA OF OTA PALACE
Àkọlé àwòrán Obalanlege ṣe abẹwo si Ọọni ti Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi

Ọọni ti Ile Ife naa wa gba Ọba Obalanlege ati awọn ọba ni imọran lati ṣe ijọba wọn pẹlu ibọwọ fun aṣa ati iṣe Yoruba.

Awọn iroyin miran ti le nif si: