2019 Elections: Àjọ tó ń wo bí ìdìbò se ń lọ ní ìsẹ̀lẹ̀ náà léwu

Alàyé bí Inec yóò se náwó nínú ìbò 2019 Image copyright @Dammyadeola

Ajọ ajafẹtọ fun eto idibo ti kesi Aarẹ Muhammadui Buhari, Ile Igbimọ Asofin Agba ati kekere lorilẹede Naijiria lati wa ọna abayọ si eto isuna Ajọ INEC saaju idibo ọdun 2019.

Ajọ Movement for Transparent Election ke gbajare lori bi idiwo se n wa lori eto isuna fun Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC saaju idibo gbogboogbo.

Ajọ ajafẹtọ naa ni awọn ko igbesẹ naa nitori ọgọrun ọjọ lo ku ki idibo gbogboogbo o waye, ti iINEC ko si tii gba owo eto isuna wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld Toilet Day: Aráàlú ní woléwolé yẹ kó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ojúlé dé ojúlé

Ninu ọrọ wọn, Ajọ naa ni igbese yii fihan pe awọn oloselu ko ka orilẹede Naijiria si, ati wi pe igbese yii le fa ifasẹyin fun idibo gbogboogbo lọdun to n bọ.

Wo àlàyé bí Inec yóò se náwó nínú ìbò 2019

Yoruba ni ti a ba ta, aa tọ ni, nitori ti a ba pa, ti a ko tọ, o lee di ẹran onidin.

Kii se iroyin tun tun mọ pe ọdun 2019 to n bọ, ni eto idibo gbogbo-gboo ni orilẹede Naijiria yoo waye sugbọn o yẹ ki awọn araalu mọ iye owo ti ajọ eleto idibo ilẹ wa Inec, ya sọtọ lati se eto isuna naa, ati atupalẹ alaye lori bi eto isuna naa yoo se lọ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMegabite: Ilé-ìwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ

Owo to le ni billiọnu lọna ojilenirinwo ati meji (N242bn) ni aarẹ Muhammadu Buhari gbe kalẹ siwaju ile asoju apapọ ilẹ wa, gẹgẹ bii owo isuna fun ajọ eleto idibo Naijiria, Inec, feto idibo ọdun to n bọ.

Awọn koko ohun to si yẹ kẹ mọ nipa bi wọn se na owo naa niyi:

Atupalẹ bi ajọ Inec yoo se na owo isuna feto idibo 2019

 • N31,49bn lo wa fun titẹ awọn iwe idibo ti wọn yoo lo feto idibo 2019, owo yii si lo pọ julọ ninu eto isuna naa
 • N7.4bn ni wọn ya sọtọ fawọn inawo pẹpẹ pẹ fun ipalẹmọ feto idibo naa. Owo yii si lo pọ julọ sikeji ninu eto isuna naa
 • N6.125bn ni owo to pọ sikẹta ninu isuna Inec, ohun si ni wọn yoo lo lati ra awọn ohun eelo idibo ti ko gba ẹlẹgẹN6bn ni Inec yoo fi bọ awọn ọlọpa ninu eto idibo 2019
 • N5.1bn ni wọn yoo fi se eto ilanilọyẹ fawọn oludiboN4.36bn ni Inec yoo fi tẹ iwe ti wọn yoo kọ esi ibo si
 • N2.9bn lo wa fun igbaradi idibo 2019N2bn ni wọn yoo fi san owo ajẹmọnu lọjọ ibo
 • N1.79bn ni wọn yoo fi san owo ọ̀yà fawọn agbẹjọroN1.6bn ni wọn yoo fi tẹ iwe akọsil orukọ oludibo
 • N972m lo wa fun titẹ iwe atọna feto idiboN840m lo wa fun rira awọn irinsẹ feto idibo
 • N730m ni wọn ya sọtọ bii ẹnawo fun yara ti wọn yoo ti maa tọpinpin bi nkan se n lọ si lasiko iboN710m ni owo fun itaniji awọn oludibo
 • N700m ni owo to wa fun ẹnawo awọn ọmọ ilẹ okeere ti yoo tọpinpin eto idibo 2019
 • N630m ni Inec yoo na lori titọpinpin awọn eto idibo abẹnu ẹlẹgbẹjẹgbẹ oselu saaju ibo 2019
 • N587m ni owo fun itankẹlẹ iroyin jake-jado Naijiria
 • N495m ni wọn yoo fi seto iranwọ fawọn osisẹ ajọ Inec to n kopa ninu eto idibo
 • N286m wa fun sise amojuto eto idibo
 • N160.7 ni wọn ya sọtọ fun titọpinpin owo tawọn oloselu yoo na fun ipolongo ibo
 • N149m ni owo to wa fun ipolowo ibo 2019
 • N125m ni Inec yoo fi se ifikunlikun pẹlu awọn onikọ-jikọ
 • N94m lo wa fun fifi atẹjisẹ ransẹ lati ori ẹrọ ibaraẹni sọrọ
 • N55m lo wa fawọn osisẹ to n seto ipalẹmọ fawọn irinsẹ idibo
 • N50m ni owo ti wọn yoo fi tẹ ikede iwe lati wa gba isẹ (Tender) fawọn agbasẹse ti yoo nifẹ lati gba isẹ titẹ iwe idibo
 • N1000 ni owo ti wọn yoo san lowo ajẹmọnu fawọn ọlọpa

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Ninu iroyin miran ẹwẹ, aarẹ Muhammadu Buhari ti pasẹ pe ki awọn ileese ijọba fi eto isuna wọn ranse ni kia kia si ile asofin, o pe tan, ọjọ Ẹti.

Idi ni pe eto isuna lọpọ igba a ma se idiwọ fun eto isejọba lorilẹẹde Naijiria.

Bakanna lo pasẹ pe ki gbogbo awọn adari ile isẹ ijọba farahan niwaju ile asofin ni kia kia .

Akọwe agba fun ijọba apapọ, ọgbẹni Boss Mustapha lo fi ọrọ na sita ninu atẹjade kan to fi sọwọ si awọn akọroyin labuja.

Mustapha ni, o ti de etigbọ ijọba pe awọn olori ileesẹ ijọba kan kọ lati mu asẹ yi sẹ.

O wa pasẹ pe ki wọn ri wi pe wọn pese ẹda eto isuna naa fun ile asofin ni kia kia.

Idaraenilebi wọpọ lori isuna ọdun 2018 laarin ijoba ati awọn asofin.

Lai pe yi ni Aarẹ Buhari ati awọn asaaju ile asofin jijọ se ipade lori bi eto isuna naa yoo ti se dofin ni kia kia.

Awọn igbese to ti waye lori isuna 2018

 • Losu keje ọdun 2017, Minister feto isuna so pe ijọba yoo fi eto isuna ranse losu kẹwa ọdun 2018
 • Losu kọkanla ọdun 2017, Aare Buhari se agbekale isuna ọdun 2018 ni iwaju igbimo apapọ ile asofin
 • Losu kejila odun 207, ile asofin agba ni, o se se ki ipenija wa fun isuna odun 2018 pelu bi awọn olori ileese ijọba se ko lati wa salaye ọrọ lori isuna wọn
 • Losu kinni odun 2018, akọwe agba fun ijọba apapọ ọgbẹni Boss Mustapha ni ijọba n se iyemeji lori amulo ilana to kuna nigbati wọn ba buwọlu isuna 2018
 • Losu keta odun 2018, Aarẹ Buhari ati awọn olori ile asofin se ipade lori isuna 2018