Leah Sharibu - 'Ìbànújẹ́ ni ohùn ọmọ wa tí a gbọ́ jẹ́ fún wa'

Awọn akẹkọbirin Dapchi

Oríṣun àwòrán, ISAAC LINUS ABRAK

Àkọlé àwòrán,

Baba Leah Sharibu rọ ìjọba lati gba ọmọ oun

Ileeṣẹ Aarẹ Naijiria ni awọn oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti n ṣe ayẹwo 'oohun Leah Sharibu' to gba igboro kan.

Ijọba apapọ Naijiria ni lootọ ni awọn gbọ nipa fọnran kan to niṣe pẹlu akẹkọbinrin Dapchi to ku si ahamọ ikọ Boko Haram, Leah Sharibu.

Ileeṣẹ Aarẹ, ninu ọrọ kan ti oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu fi sita loju opo Twitter rẹ, ni ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti n ṣe itupalẹ oohun naa. O ni ''esi ti wọn ba mu jade ninu iwadi wọn ni yoo sọ ohun ti a o ṣe lori ọrọ naa.

Ati pe Aarẹ Buhari ko ni sinmi titi ti gbogbo awọn ọmọbinrin wa yoo fi gba itusilẹ.''

Ìbànújẹ́ ni ohùn ọmọ wa tí a gbọ́ jẹ́ fún wa - Nathan Sharibu

Oríṣun àwòrán, ISAAC LINUS ABRAK

Àkọlé àwòrán,

Awọn kan ninu awọn obi awọn akẹkọbirin Dapchi n sukun ayọ

Ìbánújẹ, ìpòrúuru, ìrètí àti ìmọkanle ní àwọn ìmọlára tí ènìyàn yóò ni bí ènìyàn bá dé ilé àwọn Baba Leah, lẹ́yìn ti fọnran ohùn Leah jáde fún ìjọba oríilẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Àkọlé fídíò,

'Ògidì ọmọ Yorùbá ni mí, kò sí ọ̀rọ̀ tí n kò lè túmọ̀'

Nathan Sharibu, bàbá Leah Sharibu, sàláyè fún BBC lálẹ́ pé, 'ìnú wá bàjẹ́ gidigidi nínú ìdílé yìí, ìyàwó mi ní ìpòrúru ókàn nigbà tí ó gbọ́ ohùn ọmọ wa, kò rí ọmọ wa.

Sùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọkunrin mo ní ìmọ́kàn le díẹ̀ wà fún mi nígbà ti'mo gbọ́ ohùn rẹ̀. Mo ti ròó pé kò sí láàyè mọ ni, sùgbọ́n mo mọ̀ pé ohùn ọmọ mi ni mo gbọ́.'

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ìpòrúuru bá ìyàwó mi bó ṣe gbọ ohun ọmọ wa - Baba Leah

Ìroyìn tó jáde láti ile ìròyìn Cable lalẹ́ ọjọ́ Ajé gbé ohun Leah to ti wà ni àhámọ Boko Haram láti inú oṣù kejì pèlú àwọn ọmọ Dapchi tó lé ni ọgọ́rùn tí wọn ti tú sílẹ̀.

'Ohùn Leah mi ni mo gbọ́ nínú fọ́nran Boko Haram'

Oríṣun àwòrán, ISAAC LINUS ABRAK

Àkọlé àwòrán,

Baba Leah Sharibu rọ ìjọba lati gba ọmọ oun

Ọmọ kan tó kù ni àhámọ́ Boko Haram nínú àwọn akẹ́kọ̀ Dapchi, Leah Sharibu ti rọ ijọba lati gba kúro ninu àhámọ.

Nínú fọnran ohùn kan tó wà nígboro ní Leah Sharibu tí ń rọ ìjọba orilẹ̀-èdè Nàìjíríà láti yọ ohun kúrò lọ́wọ́ ikọ̀ Boko Haram.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti BBC ṣe fún Baba Leah, Nathan Sharibu lánàá fi han pé ohùn ọmọ òhun ni ó wà nínú fọ́nran náà.

Agbẹnusọ fún ààrẹ Muhammadu Buhari,Garba Shehu sàlàyé pé àwọn sì ń wo fọ́nràn náà wò bóyá ohun Leah ni

Nínú fọ́nrán náà Leah ń bẹ ààrẹ Muhammadu Buhari lati ṣàánú nítori ìdílé òhun

Ìròyin fi han pé wọn fi Sharíbù sáhàmaọ́ nítori o kọ̀ la'ti ṣẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú ẹ̀sin Kristiẹni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ìpòrúuru bá ìyàwó mi bó ṣe gbọ ohun ọmọ wa

Akẹkọ Dapchi mọkanlelọgọrun lo pada de

Ijọba apapọ Naijiria ti fi atẹjade kan sita wi pe awọn akẹkọbirin mọkanlelọgọrun ninu awọn akẹkọ Dapchi ni wọn ikọ Boko Haram tu silẹ l'Ọjọru (Wednesday).

Ninu atẹjade kan to jade nilu Abuja l'Ọjọru, eyi ti Sẹgun Adeyẹmi, to jẹ oluranlọwọ pataki fun minisita feto iroyin ati asa, Alhaji Lai Mohammed, fi sọwọ, sọọ di mimọ pe akẹkọ mọkọlelọgọrun ninu aadọfa awọn akẹkọ ti wọn ji gbe naa, ni akọsilẹ wa fun pe wọn ji gbe.

Alhaji Lai Mohammed ti kọkọ kede wi pe awọn akẹkọbirin mẹrindinlọgọrin ni ikọ Boko Haram tu silẹ l'owurọ Ọjọru ki wọn o to kede wi pe mọkanlelọgọrun ni awọn akẹkọbirin ti wọn da silẹ.

Iwa ipa ko le gba awọn akẹkọ Dapchi pada

O ni wọn da awọn akẹkọbinrin naa silẹ ni nkan bi aago mẹta oru pẹlu iranlọwọ awọn ọrẹ orilẹede Naijiria, ati pe ijọba ko san kọbọ fun itusilẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, Ijọba ipinlẹ Yobe

Àkọlé àwòrán,

Ijọba Naijiria sọ wipe ẹrindinlọgọrin ṣi ni akọsilẹ wa fun

Alhaji Lai Mohammed ni, "Ki itusilẹ naa le fidimulẹ, ijọba loye pe, iwa ipa ati igboju agan sira ẹni ko le jẹ ọna abayọ nitori pe o le fi ẹmi awọn ọmọbinrin naa sinu ewu.

"Eyi lo si mu ki igbesẹ pẹlẹ putu jẹ ọna to ṣe itẹwọgba.

"Laarin asiko ti wọn fi n ko awọn ọmọ naa pada, idaduro ba awọn nkankan l'awọn agbegbe kan lati le ri daju pe ko si idiwọ kankan, ati pe ko si ẹmi to s'ofo."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Bakanna lo ni atunṣe yoo ba iye akẹkọ to gba ominira ninu awọn ọmọbinrin naa lẹyin ti awọn yooku wọn ba ti ni akọsilẹ, paapa nitori pe wọn ko yọnda awọn ọmọ naa fun ẹnikẹni, wọn kan ja wọn da silẹ ni Dapchi ni.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji, ọdun 2018 ni ikọ agbesunmọmi Boko Haram ji awọn akẹkọbinrin naa gbe nileewe wọn to wa ni ilu Dapchi, nipinlẹ Yobe.