AfCFTA: Orilẹẹde 44 t'ọwọ bọ'we ilana okoowo tuntun fun Afrika

Aworan awọn orilẹẹde Afrika Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orilẹẹde metadinlogbon lo fowo si karakata lai si idiwo laarin awọn orilẹẹde

Orilẹẹde mẹrinlelogoji loti tọwọ bọwe manigbagbe adehun ilana okoowo tuntun fun Afrika eyi ti yoo mu irọrun ba karakata nilẹ Afrika.

Adehun naa ni wọn ro wipe yoo ṣe iranwọ fun ọja tita laarin awọn eniyan to le ni biliọnu kan pẹlu ireti pe owo to le ni trilion meji dọla.

Alaye ti ile isẹ iroyin orileede Rwanda kan sọ wi pe ọrilẹẹde mẹtadinlọgbọn lo fọwọ si karakata lai si idiwọ laarin awọn orilẹẹde.

Awọn ti o'n ṣagbatẹru adehun naa n lero wi pe aadọta orilẹẹde ni yoo la'nfaani karakata ti wọn ba fọwo si adehun naa.

Saaju ki wọn to fọwọ bọ adehun naa ni Aarẹ orilẹẹde Naijiria Muhammadu Buhari ti yọwọ ninu re.

Bi Naijiria ni ti o je okan gbogi lara awọn orilẹẹde ti karakata re munadoko nile Afrika ko se kopa je ipenija nla fun adehun naa.

Olootu iroyin lori eto ọrọ aje fun ile isẹ BBC, Mathew Davies, ni iwoye wa pe adehun yi yoo mu adiku ba ainise to peleke laarin awọn ọdọ ti lawon orilẹẹde Afrika.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si:

Sugbọn o ni ipenija nla ni eleyi jẹ fun awọn ti yoo mu ala naa se.