Oniṣegun iwosan: Eefin oluṣosun lewu pupọ fun ilera awọn olugbe

Olugbe kan ni adugbo Ketu
Àkọlé àwòrán Awon olugbe yari lati kuro ni adugbo won

Awọn oniṣegun iwosan oyinbo ti n ṣe ikilọ fun awọn olugbe ni ayika Olusosun lati yẹra fun eefin ina ti o le fa ipalara ni agbegbe naa lẹyin ti ile idalẹsi yi gba'na jẹ lọsẹ to kọja.

O kere ju awọn agbegbe mẹwa ni ayika Ojota, Ketu, Magodo, Mile 12, Olusosun ati awọn ẹya ara Alausa-Oregun lọwọlọwọ ni o wa ninu eefin ti o n jade lati inu Olusosun nibiti iná ti yọ ni ọjọru ọsẹ to kọja.

Imira wa fun awon eniyan lati riran ti eefin naa si gbalẹ ka to mu oju ọjọ ṣu biribiri. Awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti n wa ninu sunkẹrẹ-fa-kẹrẹ latari okunkun ti o a n waye nibẹ.

Awọn olugbe adugbo nlo awọn aṣọ pelebe lati bo imu lati dẹkun fifun eefin naa simu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption‘Ọmọ meji daku ninu eefi Olusosun’- Olugbe agbeegbe naa

Ṣugbọn dokita kan, Femi Olusoji sọ fun BBC pe awọn olugbe gbọdọ yẹra fun ipalara ti fifa eefin yii simu maa n fa.

O kilọ wipe fifa iru iru eefin bẹ naa jẹ ohun ti o buru fun ilera eniyan.

"Awọn eniyan gbọdọ wa ọna lati daabo bo ara wọn, paapaa awọn ọmọde nipa fifa eefin naa.

Àkọlé àwòrán Adugbo Olushosun ni Ojota

"Wọn le lọ si agbegbe miran fun igba diẹ, ki wọn si pada wa ti eefin naa ba ti walẹ", o sọ.

Ṣugbọn olugbe kan ni adugbo Ikosi, ti o kọ lati fun wa ni orukọ rẹ, sọ pe oun ko lee fi ile oun silẹ lọ si agbegbe miiran nitori iṣoro ati ri ile miran nilu Eko.

O sọ pe wọn ko le ṣii awọn ferese wọn tabi awọn ilẹkun fun afẹfẹ tutu nitoripe ayika wọn nigbagbogbo ni oorun ati eefin.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oniṣegun iwosan: eefin oluṣhosun lewu pupọ fun ilera awọn olugbe

Nibayi, awọn ẹdun kan wa pe egbegberun awọn ọmọ ile-iwe ni awọn ile-iwe ijọba ati awọn ile-iwe aladani ti o wa nitosi aaye naa ati awọn to n ṣiṣẹ ni ayika yi ni o ni ewu awọn arun ẹdọfóró.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: