AfCFTA: Buhari gbe igbimọ kalẹ lori adehun okoowo ọfẹ

Aarẹ Buhari joko nibi ipade igbimọ isejọba apapọ Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Naijiria dawọduro lori adehun naa lẹyin ariwo latọdọ awọn ẹgbẹ osisẹ ati olokoowo gbogbo

Ijọba apapọ ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo jiroro pẹlu awọn alẹnulọrọ atawọn leekan leekan to fimọ igun gbogbo to nii se pẹlu ọrọ titọwọ bọwe adehun eto karakata ọfẹ ni ilẹ Afirika, (AfCFTA).

Aarẹ Buhari lo se akojọpọ igbimọ naa nibi ipade igbimọ alasẹ ijọba orilẹede Naijiria nilu Abuja.

Aarẹ Buhari ni, o yẹ ki ijọba tubọ se agbeyẹwo atubọtan titọwọ bọ iwe adehun naa lori ọrọ aje ati eto aabo lorilẹede Naijiria.

Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari ni ko si adehun to se koko ju abo ati igbelewọn eto ọrọ aje orilẹede Naijiria lọ

Aarẹ Buhari ni isejọba orilẹede Naijiria ko ni faramọ ohunkohun ti yoo ba mu eebu ẹyin idagbasoke awọn oludaleesẹ silẹ atawọn olokoowo gbogbo labẹle.

Bakanna lo ni, ko si bi o ti lee wu ko ri, ijọba yoo ni faaye gba ohunkohun ti yoo sọ orilẹede Naijiria di akitan, ti tọtun-tosi yoo maa wa da awọn ohun eelo si, eleyi to ni o seese ko sakoba fun awọn ileesẹ to sẹsẹ n gberu labẹle.

Awọn orilẹede Afirika buwọlu adehun AfCFTA

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Naijiria ati awọn orilẹede mẹsan miran wa ninu awọn ti ko tii tọwọ bọ iwe adehun AfCFTA

Amọsa, awọn ogoji orilẹede ilẹ Afirika tọwọ bọ iwe adehun eto karakata ọfẹ ni ilẹ Afirika, (AfCFTA) eleyi to seese ko se atọna fun idasilẹ agbegbe karakata to tobi julọ lagbaye.

Orilẹede mẹwa, ninu eyi ti Naijiria wa ninu wọn, ni wọn ti kọ lati tọwọ bọ iwe adehun naa.

O si di dandan ki gbogbo awọn orilẹede ti wọn wa nilẹ Afirika lati tọwọ bọwe adehun yii, ko to lee d'ohun.