PDP: Ẹsun tijọba fi kan Ekweremadu nii se pẹlu ibo 2019

Sẹnetọ Ekweremadu n sọrọ nile asofin agba

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate

Àkọlé àwòrán,

Dukia mẹsan ni wọn ni Ekweremadu ko se akọsilẹ rẹ niwaju ijọba

Lọjọru ni ijọba apapọ gba ileẹjọ lọ lori ẹsun pe igbakeji aarẹ ile asofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnetọ Ike Ekweremadu ko se akọsilẹ awọn dukia rẹ kan ko to de ipo gẹgẹbii ofin ti se laa kalẹ.

Nibayii ẹgbẹ oselu Peoples Democratic Party, PDP to jẹ asiwaju ẹgbẹ oselu alatako lorilẹede Naijiria ti sapejuwe igbesẹ naa gẹgẹbii ara awọn ọna ti ẹgbẹ oselu APC to n sejọba lorilẹede naijiria n gba lati dun mọhurumọhuru mọ awọn to ba n gboo lẹnu.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, igbakeji akọwe ipolongo fun ẹgbẹ oselu PDP lorilẹede Naijiria, Diran Ọdẹyẹmi ni, "ko jẹ tuntun mọ bi ẹgbẹ ijọba aarẹ Buhari se ngbe gbogbo awọn to ba ti n tako igbesẹ fami lete n tutọ' to n gbe.'"

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ oselu PDP n woye pe ibo ọdun 2019 to n sunmọ lo sokunfa ẹsun ti wọn ka si Ekweremadu lọrun

"Saaju, aarẹ ile asofin agba, Bukọla Saraki ni wọn kọkọ wọ lọ siwaju ileẹjọ lori ẹsun pe ko se akọsilẹ dukia rẹ nitori pe o n gbo wọn lẹnu, nisinsin yii ti igbakeji rẹ, Ekweremadu ko jẹ ki wọn gbadun mọ loun naa tun ti di ẹni ti wọn n wokoko mọ bayii."

Ẹgbẹ oselu PDP ni, ọgbọn ati mu gbogbo awọn to lee yi APC lagbo da sina lasiko ibo apapọ to nbọ nijọba apapọ nfi awọn 'ẹsun ti ko lẹsẹ nlẹ kan ko lee ri ọna pada si ijọba.

"Ọdun kẹta niyi ti Ekweremadu ti wa ni ipo gẹgẹbii igbakeji aarẹ ile igbimọ asofin agba, o se jẹ iasiko yii gan-an ni wọn sẹsẹ rina rii wi pe, ko se akọsilẹ awọn dukia rẹ niwaju ijọba. Ara awọn ọna lati ko awọn alatako layajẹ niyi."

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Sẹnetọ Bukọla Saraki pẹlu n jẹjọ lori ẹsun aise akọsilẹ dukia rẹ

"Ka ni Aarẹ ana, Goodluck Jonathan pẹlu se bẹẹ, se awọn naa lee ri ijọba se?"

Ijọba apapọ nfi ẹsun kan igbakeji aarẹ ile igbimọ asofin agba Naijiria, Sẹnetọ Ike Ekweremadu pe o kuna lati se akọsilẹ awọn dukia rẹ fun ijọba.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Àkọlé fídíò,

Ẹni ti ko riran to nlọ'ta ni Mushin

Mẹsan lawọn dukia ti ijọba apapọ n tọka si bayii, ti wọn wa kaakiri ilu bii Abuja, ilẹ Gẹẹsi, Dubai ati Florida lorilẹede Amẹrika.