Iyan South Sudan: Eeyan miliọnu mẹfa ni ebi nba finra

Ọmọde kan joko sori ibusun pẹlu awọn olutọju alaisan kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Miliọnu marun lawọn ti ohun elo iranwọ n de ọdọ wọn lorilẹede South Sudan

Nkan bii ilaji awọn eeyan orilẹede South Sudan lo seese ko fara kaasa iyan eyiun bi iranwọ to tọ ko ba tete de ọdọ wọn.

Ajọ to n mojuto igbayegbadun awọn atipo lorilẹede Norway lo sọ bẹẹ.

Ajọ naa ni, o le ni miliọnu mẹfa awọn eeyan orilẹede South Sudan ti ọwọngogo ounjẹ n ba finra atipe miliọnu kan eeyan miran lee kun wọn laarin osu mẹta si asiko yii.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ajọ to n mojuto igbayegbadun awọn atipo lorilẹede Norway salaye wi pe, o din ni ilaji awọn eeyan orilẹede naa to ri awọn ohun elo iranwọ ti wọn nko ransẹ si wọn gba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nkan bii miliọnu mẹrin lawọn eeyan ti ogun ti le kuro nile lorilẹede Sudan

O ni awọn agbegbe ti wahala ọwọngogo ounjẹ yii n ba finra julọ lawọn ibi ti rogbodiyan ogun ti n waye lorilẹede South Sudan.

Ajọ naa ni ogun abẹle ọdun mẹrin to n waye nibẹ ko ran isẹlẹ naa lọwọ rara.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ni ọdun 2013 logun abẹle bẹ silẹ lorilẹede South Sudan

Ọpọ igba ni wọn ti fi ẹsun kan ijọba orilẹede ọhun pe o ndena eto iranwọ ti wọn fi nransẹ sawọn agbegbe kan, ti awọn agbẹ si tun ti sa kuro ni oko wọn pẹlu ibẹru fun ẹmi wọn eleyi to ti mu adinku nlanla ba ipese ounjẹ nibẹ.

Ko din ni miliọnu meji awọn eniyan ti ogun abẹle ti le kuro ni ile wọn lorilẹede South Sudan, bẹẹni ọpọ miran lo tun ti sa fi orilẹede naa silẹ patapata lọ sorilẹede miran.