CBN:Àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ yóò pín 220 bílíọ̀nù Náírà

Owo Naira

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Asofin fọwọ s'orukọ awọn mẹta fun igbimọ isakoso CBN

Ilé ìfowópamọ àpapọ̀ fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (CBN) sọ pé òhun ti ṣètò bílíọ̀nù ogúnlénigba náírà silẹ̀ fún àwọn olókoòwò kéékèké.

Isaac Okarafor to jẹ́ adarí ibaraẹnisọ̀rọ̀ ní CBN lo kédé ètò náà lasiko tó ń ba àwọn akọròyìn sọ̀rọ̀ ní ìpínll Gombe, Ó ní wọn ó pín owó náà fún àwọn ẹgbẹ́ alájẹṣẹ́kù lábẹ àwọn ilé ìfowópamọ tó ń ri sí àwọn olókoòwò kéékèké.

O ní CBN ya owó náà sọ́ts lati fi ran àwọn oníṣẹ́ ọwọ lọ́wọ́ ni, tó fi mọ àwọn to ń pọ taya, àwọn tó ń dírun, àti àwọn ṣe onírúurú iṣẹ́ ọwọ. Isaac rọ wọn láti fí orúkọ sílẹ̀ fún èyáwó náà nítori pé kò ni rọrun fún wọn lati rí irú owó bẹ́ẹ̀ gbà ní àwọn ilé ìfowópamọ ńlá.

Oríṣun àwòrán, Central Bank of Nigeria

Àkọlé àwòrán,

Ile ko sọ idi ti ko fi fọwọ si orukọ ọkan lara awọn ti aarẹ Buhari fi ransẹ gẹgẹbii ọmọ igbimọ isakoso banki apapọ orilẹede Naijiria

Aṣofin fọwọsi igbakeji gomina meji

Oríṣun àwòrán, Central Bank of Nigeria

Àkọlé àwòrán,

Awọn asofin agba tun fọwọ si orukọ awọn mẹta fun igbimọ isakoso banki apapọ Naijiria

Ile igbimọ asofin agba orilẹede Naijiria ti fọwọsi orukọ awọn igbakeji gomina tuntun meji fun banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN.

Awọn meji ọhun ni Arabinrin Aishah Ahmad ati Ọgbẹni Edward Lametek Adamu to jẹ osisẹ Banki apapọ naa, sugbọn ti wọn fun ni igbega si ipo tuntun naa.

Bakannaa ni awọn asofin agba tun se ayẹwo orukọ Ọjọgbọn Adeola Festus Adenikinju, Ọmọwe Aliyu Rafindadi Sanusi, Ọmọwe Robert Chikwendu Asogwa, Ọmọwe Asheikh A. Maidugu gẹgẹbii ọmọ igbimọ oludari banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN.

Lẹyin o rẹyin ati pẹlu igbekalẹ abọ iwadi igbimọ ti ile gbe kalẹ lori ọrọ isuna, amojuto Banki ati ileesẹ adojutofo, awọn asofin agba buwọlu orukọ Ọjọgbọn Adeola Festus Adenikinju, Ọmọwe Aliyu Rafindadi Sanusi ati Ọmọwe Robert Chikwendu Asogwa ti wọn si wọgile orukọ Ọmọwe Asheikh A. Maidugu.

Wọn wa ke si aarẹ Buhari lati tete fi orukọ elomiran ti yoo rọpo Maidugu sọwọ, ki igbimọ naa lee pe lati se isẹ rẹ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: