Awọn agbebọn pa ọmọ ogun 12 ni Birnin Gwari

Aworanm ọmọ ogun orilẹẹde Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọlu laarin awọn ọmọ ogun orilẹẹde Naijiria ati awọn agbebọn lariwa Naijiria ki se oun ajoji.

Awọn ọmọ ogun mejila la gbo pe awọn agbebọn seku pa nigba ti wọn kọlu wọn ni abule Konmpanin Doka ni ijọba ibile Birnin- Gwari, nilu Kaduna.

Bakaana ni wọn ni ọmọ ogun mẹrin farapa ninu isẹlẹ naa to waye lalẹ ọjọ isẹgun.

BBC Yoruba gbiyanju lati ba agbẹnuso fun ile isẹ ọmọ ogun ori ilẹ ọgagun John Chukwu sọrọ sugbọn o ni oun ko ti le fesi sọrọ naa.

Awọn kan ti ọrọ naa soju wọn ni awọn agbebọn naa doju ija kọ ibudo awọn ọmọ ogun to wa ni Doka, lagbegbe kan to wa laarin Funtua ati Birnin Gwari, ti wọn si pa awọn ọmo ogun to wa nibe.

Sugbọn ijọba ipinle Kaduna ti fesi sọrọ naa.

Ninu atejade kan ti agbẹnuso fun Gomina Ahmed El Rufai, Samuel Aruwan fi sọwọ si awọn akọroyin,o ni Gomina El Rufai ti bọ kanje lori isele naa o si pe fun, to si pe fun ifọwọsowọpọ pelu awọn eleto aabo lati koju iwa janduku.