Niyi Akintọla: Atunse ofin lo le dẹkun jẹgudujẹra

Aworan odiwọn owo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹjo jegudujera wa lara awọn eyi ti opo ni Naijiria ma nf'ọkan tele

Amofin agba kan lorilẹẹde Naijiria ti pe fun agbeyẹwo ofin gẹgẹ bi ọna lati dẹkun iwa jẹgudujẹra lawujọ.

Amofin Niyi Akintola woye ọrọ naa nigba to nwoye lori bi ile ẹjo kan nilu Abuja se yi idajo pada lori ẹsun ikowoje ti wọn fi kan osise kan nileesẹ to nsakoso owo ifẹyinti awọn ọlọpaa kan, ogbẹni Yakubu Yusuf.

Saaju ni adajo ile ejo giga kan labuja ti dajo ewọn ọdun meji tabi owo itanran ọtalelẹẹdẹgbẹrin o din mẹwa nair (N750,000) fun-un, lori ẹsun pe o lu biliọnu mẹrinlelogun naira owo ifẹyinti ọlọpaa ni ponpo.

Ninu idajọ tuntun naa, adajọ ile ẹjo kotẹmilorun, adajo Abdul Aboki, ni ki Yusuf lo fi ẹwon ọdun mẹfa gbara, ko si da owo biliọnu mejilelogun pada.

Akintola ni, kii se ẹbi adajọ pe ijiya lọpọ igba lori ẹsun kikowo je, ki farajọ bi ẹse ti se wuwo si.

'ilana ofin nipa ẹjọ ti wọn ba ti gbe wọn lo si iwaju adajọ ni wọn gbodo tele. Bi iwe ofin ba ti se la ijiya kale ni adajọ yoo se tele. Ko le m'ofin tire wa yato si eyi to wa ninu ofin''

Akintola ni asiko ti to bayi lati wa wọrọko fi sada lori ofin ile Naijiria eyi ti ''ọpọ ninu wọn ko ba ilana ofin ode oni mu''

Idajo pataki re fun awọn osisefeyinti

Ajo to ngbogun ti iwa ibaje lorileede Naijiria, EFCC kan sara si idajọ tuntun naa loju opo twita re

Awọn ọmọ Naijiria naa si f'ero ọkan wọn han

O ti to ọdun marun ti wọn ti wa lori ẹjo ọgbẹni Yakubu Yusuf.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Biliọnu mẹtalelọgbọn ni iye owo ti wọn ni o koje.

Lẹyin ti o jẹwo pe oun ji biliọnu meji, ile ẹjo giga dajọ ẹwọn ọdun meji fun tabi owo itanran ọtalelẹẹdẹgbẹrin o din mẹwa naira.

Ọrọ naa bi ọpọ eeyan ninu to fi mo ajọ to nse akoso ẹka idajọ to ni ki adajọ to da ẹjo naa lo rọọkun nile fun ọdun kan lori idajọ to da.