Awọn ọmọbinrin Dapchi de s'Abuja, funpade pẹlu Aarẹ Buhari

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọbinrin Dapchi: Mi o lọ sile iwe mọ

Ni bayi, awọn ọmọbinrin ile-iwe ti awọn Boko Haram tu silẹ ni Dapchi, nipinlẹ Yobe ti wa ni'lu Abuja lati pade Aarẹ Muhammadu Buhari.

Minisita fun ọrọ iroyin ati eto aṣa, Lai Mohammed sọ pe awọn ọmọbinrin marunlelọgọrun ati ọmọdekunrin kan ni wọn gba ominira lọwọ Boko Haram.

Ko tii si aridaju nipa ayanmọ ati ipo awọn ọmọbinrin marun ti o ku ninu awọn ti wọn jigbe pẹlu awọn iroyin wipe wọn ti ku si igbekun.

Ọmọbinrin kan ṣi wa nigbekun nitoripe o kọ lati tako ẹsin Kristiẹni.

Oniroyin BBC, Chris Ewokor j'abọ wipe awọn ọmọbinrin de si ilu Abuja lati Maiduguri ni alẹ ọjọru. Wọn dẹ ti n ṣe awọn ayẹwo ati iwadii ipo ilera wọn ṣaaju ki wọn to o pade Aarẹ Muhammadu Buhari.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Aare Buhari yoo sepade fun pelu won loni
Image copyright Isaac Linus Abrak
Àkọlé àwòrán Ekun gba'gboro ka lori oro awon omobinrin Dapchi

Ti ijọba apapọ si sọ pe oun ko san owo kankan fun igbasilẹ wọn. Ṣugbọn ariyanjiyan ti n waye lori alaye ijọba pe awọn ko san owo fun igbasilẹ awọn ọmọbinrin yi.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: