Adajọ Kenya paṣẹ $25,000 fun oloyun ti wọn fiya jẹ nile iwosan

Josephine Majani nile ẹjọ Image copyright Fredrik Lerneryd
Àkọlé àwòrán Ọkan lara awọn to n gba iwosan ya fidio rẹ si ẹrọ ilewọ

Ile-ẹjọ kan ni orilẹede Kenya ti da ẹjọ ki ijọba o san iye ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn owo ile Amerika, (9,000,000.00 naira) fun obinrin oloyun ti wọn fi iya jẹ ni ile iwosan ijọba lọdun marun sẹyin.

Awọn ọrọ to jẹ mọ ifiya jẹ awọn to n gba itọju wọpọ lawọn ile iwosan lorilẹede naa.

Akọroyin BBC, Victor Kenani to wa ni olu-ilu Kenya, Nairobi jabọ wipe adajọ ile-ẹjọ giga to wa ni Bungoma, Abida Aroni sọ wipe awọn oṣiṣẹ ile iwosan naa tẹ ẹtọ obinrin naa mọlẹ, bii wọn ṣe kọ obinrin naa silẹ lasiko irọbi ni ile iwosan ijọba lọdun 2013.

Adajọ naa ni obinrin oloyun ti orukọ rẹ n jẹ Josephine Majani ni ẹtọ si eto iwosan to peye ati iyi to yẹ ọmọ eniyan ati wipe awọn ẹtọ yii ni ijọba orilẹede naa fi gbo'lẹ nigba to n rọbi rọlọ ni ile-iwosan to wa ni Bungoma ni iwọ oorun Kenya.

Image copyright Fredrik Lerneryd
Àkọlé àwòrán Adajọ Kenya paṣẹ $25,000 fun oloyun tan fi'ya jẹ nile iwosan

Adajọ naa ni ki wọn fun arabinrin naa ni owo-gba-mabinu ti o to ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn owo orilẹede Amerika, nitori inira ti wọn jẹ ki obinrin naa o la kọja.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Josephine nigba to n s'ọrọ nile ẹjọ naa ni wipe awọn nọọsi alabẹrẹ gba oun loju niwaju gbogbo awọn eniyan, ti wọn ko si ṣe iranwọ kankan fun oun nigba to n rọbi ni ilẹ nlẹ ile-iwosan naa.

Amọ, gbogbo iya ti wọn fi jẹ arabinrin naa ni ọkan lara awọn to n gba iwosan ya fidio rẹ si ẹrọ ilewọ rẹ.

Iroyin fi lede wipe eto iwosan mẹhẹ lorilẹede naa, ti ọpọlọpọ ile-iwosan ko si ni ohun igbalode lati tọju awọn to nilo itọju.