Koko iroyin: Awuyewuye Dapchi, alaboyun tan’gbaloju nibi irọbi

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.

'Jibiti ni iẹlẹ Dapchi, kii e ootọ'

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ni bayi, awọn ọmọbinrin ile-iwe ti awọn Boko Haram tu silẹ ni Dapchi, nipinlẹ Yobe ti wa ni'lu Abuja lati pade Aarẹ Muhammadu Buhari, ṣugbọn ọpọlọpọ ariyanjiyan lo wa lori itusilẹ awọn ọmọbinrin naa.

Ijọba apapọ sọ wipe awọn o san owo kankan lati gba awọn akẹẹkọ naa kuro ni igbekun Boko Haram.

Nigbati ẹgbẹ oṣelu alatako gboogi ni Naijiria, PDP sọ wipe iṣẹlẹ bi wọn se gbe awọn akẹkọ Dapchi itusilẹ wọn mu ifura lọwọ. Ẹ wo ibi fun ẹkunrẹrẹ.

Adajọ paṣẹ $25,000 fun oloyun tan fi'ya jẹ

Ile-ẹjọ kan ni orilẹede Kenya ti da ẹjọ ki ijọba o san iye ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn owo ile Amerika, (milionu naira mẹsan) fun obinrin oloyun ti wọn fi iya jẹ ni ile iwosan ijọba lọdun marun sẹyin.

Obinrin naa, Josephine Majani, nigba to n s'ọrọ nile ẹjọ naa ni wipe awọn nọọsi alabẹrẹ gba oun loju niwaju gbogbo awọn eniyan, ti wọn ko si ṣe iranwọ kankan fun oun nigba to n rọbi ni ilẹ nlẹ ile-iwosan naa.

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Fidio wa fun toni

Aṣofin Mamora sọ wipe o yẹ ki wọn ṣe ayẹwo owo ti awọn to n ṣe ijọba n gba latori awọn aṣofin titi to fi de ori awọn adajọ.

Àkọlé fídíò,

'Emi o gba 13.5 milionu naira'

Owo oṣu rẹ melo ni wọn ma yọ ninu owo oṣu aṣofin kan lorilẹede Naijiria?

Sẹnatọ kan lorilẹede Naijiria n gba iye owo to to Millionu ẹrindinlọgọji naira lọdun.

Ti o ba n gba owo osu to kere julọ (₦18,000):

 • Yoo gba sẹnatọ kan ni wakati kan ati isẹju kan lati gba iye owo osu naa.
 • Pẹlu owo osu yii, o ma gba ọ ni odun mejilelogunlelẹẹdẹgbẹrin(722 years) ati osu meta lati gba iye owo ti sẹnatọ kan n gba lọdọọdun.
 • Kani wipe ọdun 1296 lo ti bẹrẹ isẹ, ẹ ba tii maa gba iye owo ti wọn n gba bayii.
 • Owo osu Sẹnatọ kan losu yoo ra apo irẹsi toto 866, nigbati owo osu rẹ yoo ra apo irẹsi kan.

To o ba n gba ₦50,000:

 • Yoo gba sẹnatọ ni wakati meji at isẹju mọkandinlaadọta(49) lati pa iye owo to n pa losu.
 • Pẹlu owo osu rẹ, yoo gba ọ ni odun 260 lati gba iye owo ti sẹnatọ kan n gba lọdọọdun.
 • Kani wipe o ti bẹrẹ isẹ lati Odun 1758, o ba ti maa gba iye owo won bayii
 • Iye owo sẹnatọ kan losu le ra apo iresi toto 866, nigbati iye owo osu rẹ yoo ra apo irẹsi mẹta

To o ba n gba ₦100,000:

 • Yoo gba sẹnatọ ni wakati marun ati isẹju 39 lati pa iye owo to n pa losu.
 • Pẹlu owo osu rẹ, yoo gba ọ ni odun 130 lati gba iye owo ti sẹnatọ kan n gba lọdọọdun.
 • Kani wipe o ti bẹrẹ isẹ lati ọdun 1888, o ba ti maa gba iye owo wọn bayii
 • Iye owo senato kan losu le ra apo iresi toto 866, nigbati iye owo osu rẹ yoo ra apo irẹsi mẹfa

To o ba n gba ₦150,000:

 • Yoo gba sẹnatọ ni wakati marun ati isẹju 37 lati pa iye owo to n pa losu.
 • Pẹlu owo osu rẹ, yoo gba ọ ni ọdun 86, ati osu mẹjọ lati gba iye owo ti sẹnatọ kan n gba lọdọọdun.
 • kani wipe o ti bẹrẹ isẹ lati Odun 1933, o ba ti maa gba iye owo wọn bayii
 • iye owo sẹnatọ kan losu le ra apo irẹsi toto 866, nigbati iye owo osu rẹ yoo ra apo irẹsi mẹwa

To o ba n gba ₦200,000:

 • Yoo gba sẹnatọ ni wakati 11 ati isẹju 14 lati pa iye owo to n pa losu.
 • Pẹlu owo osu rẹ, yoo gba ọ ni odun 65, ati osu mẹjo lati gba iye owo ti sẹnatọ kan n gba lọdọọdun.
 • Kani wipe o ti bẹrẹ isẹ lati ọdun 1931, o ba ti maa gba iye owo wọn bayii.
 • Iye owo sẹnatọ kan losu le ra apo irẹsi toto 866, nigbati iye owo osu rẹ yoo ra apo irẹsi mẹtala.

Elo lowo ti rẹ jẹ?

jọwọ fi owo osu re sibi
BBC koni fi iroyin to fi sọwọ si wa pamọ, ori ero re nikan ni yoo wa.

iwọ Ọgbọn ọjọ

Jẹ ka ri oun too gba

Jẹ ka ri oun too gba

Jẹ ka ri oun too gba

Lati igba ti o ti wa loju opo yii

O ti gba:

Awọn to seto yii

Olawale Malomo lo se eto yii, nigbati Manuella Bolomi ya atẹ yii

Bi a se se eto yii

A lo ọrọ ti ọkan lara awọn sẹnatọ orileede Nigeria, sẹnatọ Shehu Sani, lọjọ keje, Osu Kẹta, 2018.Iye owo ti awọn sẹnatọ n gba losu ko han si awon ara ilu.

Iye owo ilẹ Naijiria si iye owo orilẹede Amẹrika lọjọ 20, Osu Keta,2018 ni 1USD=359.200NGN ati 1GBP = 503.483NGN, pẹlu oju opo http://xe.com

Ẹrọ isiro fi lede wipe owo apo irẹsi kan jẹ ₦15,000

Pin oju ẹrọ yii

Pin oju ẹrọ yii

Njẹ o mọ?

Eyi ni pẹtẹẹsi akọkọ (storey building) lorilẹede Naijiria: