Bill, Melinda Gates: Ebi, ikú ìyálọ́mọ àti ọmọ wẹ́wẹ́ nìsòro Nàíjíríà

Bill ati Melinda Gates

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Bill Gates ati iyawo rẹ, Melinda lo da ajọ naa silẹ

Abajade kan ajọ Bill ati Melinda Gates Foundation maa n gbe jade ni ọdọọdun lori itẹsiwaju ọmọ eniyan ni agbaye ti fi han wipe nigba to ba maa di ọdun 2050, awọn ọmọ Naijiria ati Congo ni yoo jẹ ida mẹrin ninu mẹwaa awọn to toṣi ju ni agbaye.

Abajade naa ti wọn pe orukọ rẹ ni 'Goalkeepers Report' ti ọdun 2018 ni ebi, iku awọn iyalọmọ, iku ọmọ ọwọ ni o jẹ oun ti ko jẹ ki igbe aye ni orilẹede Naijiria muna d'oko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

OsunDecides: Omisore ní ẹni tó bá fẹ́ ra ìbò, àwọn yóò lọ lásọ mú ni

Abajade naa ni nigba to ba fi maa di ọdun 2050, awọn akuuṣẹ eniyan bi miliọnu mejilelaadọjọ (152 million) ni yoo wa ni orilẹede Naijiria ninu awọn eniyan bi ọgbọnlenirinwo miliọnu (429 million) ti yoo maa gbe orilẹede yii ni ọdun naa.

Oríṣun àwòrán, @NGRPresident

Àkọlé àwòrán,

Bill Gates ni ọdun mẹtalelaadọta ni ọpọ ọmọ Naijiria nku

Abajade naa ni nitori orilẹede Naijiria ko kọbi ara si idagbasoke ọmọ eniyan ni yoo fa ti iṣẹ yoo fi pọ ni orilẹede naa. Ajọ ti o ṣe iwadi lati gbe abajade naa sita, ti Bill Gates ati iyawo rẹ Melinda da silẹ lo ti n ṣe afihan ọrọ iṣẹ ati iya ni agbaye lati ọdun 2000.

Laarin ọdun 2000 titi di iwoyi, bi biliọnu kan eniyan ni ajọ naa ni o ti bọ lọwọ iṣẹ ni agbaye, ṣugbọn o jọ bi ẹni pe, ni Afrika, iṣẹ ati iya ni pọ si ni.

Àkọlé fídíò,

'Ilé ìwòsàn ṣi abẹ́rẹ́ Formalin gún mí; n kò lè dá ìgbẹ́ àti ìtọ̀ dúró mọ́'

Ò sòro láti bímọ sí Nàíjíríà - Bill Gate

Ẹ o ranti wipe, ni oṣu kẹta ọdun 2018 ni Ọgbẹni Bill Gates sapejuwe ilana imupadabọsipo ati agbega ọrọ aje tijọba apapọ dawọle gẹgẹ bii eyiti ko ba aini awọn araalu pade.

Bakanaa lo ni ko ba san fun orilẹede Naijiria ju bayi lọ, to ba jẹ pe o dokoowo pupọ lẹka eto ẹkọ ati ilera, dipo kijọba maa dojukọ ipese awọn ohun eelo taa lee fojuri, eyi to nsakoba fun idagbasoke ọmọniyan.

Gates si asọ loju ọrọ yii pẹlu alaga ajọ alaanu Dangote, Alhaji Aliko Dangote, nibi akanse ipade igbimọ awọn eleto aje lorilẹede yii eyi to waye ni gbọngan apejẹ to wa nile ijọba nilu Abuja.

Akori ipade naa, eyiti igbakeji aarẹ Yẹmi Ọsinbajo dari rẹ ni "idokowo ninu agbega ọmọniyan lati se atilẹyin fun afojusun idagbasoke ọrọ aje awọn mẹkunnu"

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Awọn gomina mẹrẹẹrindinlogoji to wa lorilẹede yi pẹlu awọn minisita tọrọ aje kan, ati gomina banki apapọ ilẹ wa lo jẹ ọmọ igbimọ naa.

Bill Gates ni, "Orilẹede Naijiria jẹ ara awọn orilẹede to lewu julọ lati bimọ lagbaye, nitori ilẹ wa lo nse ipo kẹrin lọwọlọwọ lagbaye, taa ba nsọrọ iku awọn iyalọmọ, to si n lewaju orilẹede Sierra Leone, Central African Republic ati Chad. Koda, ọkan ninu mẹta awọn ọmọde ni Naijiria ni ko ri ounjẹ asara loore jẹ."

Oríṣun àwòrán, @NGRpresident

Àkọlé àwòrán,

Bill Gates ati Aliko Dangote rọ Buhari lati dokowo ninu araalu

"Ni awọn orilẹede towo to nwọle fun wọn ti gbe pẹẹli, ọjọ ori ọpọ awọn eeyan ibẹ ki wọn to ku, maa nwọ ọdun marundinlọgọrin, lawọn orilẹede ti owo to nwọle fun wọn ko ti gbewọn to bẹẹ, ọjọ ori ọpọ wọn ki wọn to ku maa nwọ ọdun mejidinlaadọrin sugbọn lorilẹede Naijiria, ọdun mẹtalelaadọta lọpọ ọmọ Naijiria ndagbere faye."

O wa daba pe ipese awọn ohun eelo amayedẹrun gbọdọ maa lọ nifẹgbẹ-kẹgbẹ pẹlu eto idokowo ninu awọn araalu eyiti yoo mu ki ọrọ aje tọjọ.