Iná Abia: Èèyàn mẹ́rìndínlógún ló kú, tọ́pọ̀ sì farapa

Awọn panapana n pa ina to sọ lara ọpa ep Image copyright Getty Images

Ijamba ko nile, ayafi ki ọba oke maa sọ gbogbo wa.

Se ni isẹlẹ ijamba ọpa epo kan to fọ ni abule Umudaru, nijọba ibilẹ Osisioma, nipinlẹ Abia si n se awọn olugbe ibẹ ni haa-hii, nitori ẹnikan lo mọ ni isẹlẹ naa.

Ijamba naa waye lati ara ọpa epo ti wọn ti pa ti lati ọjọ pipẹ, eyi to n gbe epo pẹtiroolu lati ibudo ipọnpo Osisioma lọ si Enugu ati Kaduna, to si gba abule Umudaru ati Umuimo kọja.

Koda, bi eeyan jẹ ori ahun, yoo bu sẹkun nibi isẹlẹ naa, tori awọn oku ti wọn ti jona, ti wọn fọn kalẹ nibi ti isẹlẹ naa ti waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌyá àkàndá ẹ̀dá: Àwọn ẹbí mi fẹ́ kí n pa ọmọ mi torí ó jẹ́ àkàndá ẹ̀dá

Awọn mọlẹbi awọn eeyan to fori sọta ina to su yọ lati ara ọpa epo to bẹ naa, ti wọn si tete da oku awọn eeyan wọn mọ, ni wọn ti n gbe wọn kuro nibẹ, kawọn agbofinro to de.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, Agbẹnusọ fun ileesẹ elepo NNPC, Ndu Ughamadu, ni awọn osisẹ alaabo awọn ati ileesẹ panapana ni ipinlẹ Abia tete gbera lọ sibi isẹlẹ naa lati bomi pa ina naa.

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, Eze Benito, tii se oludari ajọ aabo ara ẹni laabo ilu, NSCDC salaye pe ẹmi mẹrindinlogun lo ba isẹlẹ naa rin.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Igba akọkọ kọ ree ti isẹlẹ ina lati ipasẹ ọpa epo tabi ọkọ eepo yoo maa ran ọpọ eeyan sọrun alakeji

"Mo gbọ pe awọn eeyan n ji epo pẹtiroolu ni ina fi sọ lagbegbe naa, to si ran eeayn mẹrindinlogun sọrun."

Ninu ọrọ rẹ, Oludari agba fun ajọ NNPC, Maikanti Baru ni isẹlẹ naa ba oun lojiji, nitori bo se ran ọpọ eeyan sọrun, to si tun ba ọkọ aimoye dukia jẹ.

Wayi o, wọn ti gbe ọpọ eeyan to fara pa nibi isẹlẹ naa lọ si ile iwosan.