2019 Election: INEC nílò owó láti gbógun ti ríra ìbò - Amòfin

Àkọlé fídíò,

Ekiti Election: Ẹ́gbẹ̀rún mẹ́rin nàirà ni ẹnikọ̀ọ̀kan ń gbà

"Ijọba Naijiria ko fun Ajọ to n bojuto eto idibo lorilẹ-ede Naijiria, INEC ni ohun ti wọn nilo lati gbogun ti iwa ibajẹ lasiko eto idibo Naijiria".

Amofin nipa eto isejọba, Deji Olambiwonnu lo sọ eyi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ọna ti eto isejọba awa-ara-wa ṣe le gbilẹ si lorilẹ-ede Naijiria.

Olambiwonnu sọ pe ohun pato to mu ki isejọba awa-ara-wa yatọ si ijọba ologun ati awọn iṣejọba miran ni ibọwọ fun ofin orilẹ-ede ẹni gẹgẹ bi adari ati ara ilu.

Àkọlé fídíò,

Ekiti Election: Ẹ́gbẹ̀rún mẹ́rin nàirà ni ẹnikọ̀ọ̀kan ń gbà

O fikun wi pe ati mẹkunu ati adari orilẹ-ede Naijiria ni isẹ lati ṣe lasiko idibo ki eto oṣelu awa ara wa le gboro si, lati dẹkun iwa ibajẹ lasiko idibo lorilẹ-ede naa.

INEC nilo owo lati gbogun ti rira ibo

Amofin Deji Olambiwonnu sọ pe rira ibo(vote-buying) tunmọ si idibo fun awọn oloselu nitori wọn fun awọn eniyan ni owo tabi wọn se ileri fun awọn ara ilu lati fun wọn ni owo tabi nkan miran.

Olabiwonnu ni Ajọ Eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC nilo iranwọ ijọba ati awọn ara ilu lati gbogun ti iwa ibajẹ ati magomago lasiko idibo.

O fikun wi pe Ajo INEC gbọdọ bẹrẹ si ni lo ijiya to wa labẹ ofin lati gbogun ti iwa rira ibo ti ohun mu ki eto ijọba awa-ara-wa mẹhẹ lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Ìran kan si ìkejì ló n gbèrò láti ṣe ìrú ìgbéyàwo àjùmọ̀ṣe 'Shao' fọ́mọ wọn

Amofin naa wa parọwa si ijọba lati pese eto abadofin ti INEC nilo lati gbogun ti iwa ibajẹ ki wọn ba le fi sikun ọw ofin mu awọn asebajẹ lasiko ibo.

"Olósèlú ìjọba àwarawa tòótó ni Goodluck Jonathan"

Aarẹ Muhammadu Buhari ti gboriyin fun Aare ana lorilẹ-ede Naijiria, Goodluck Jonathan fun bose fi tọwọtọwọ gba bi ose fidirẹmi ni idibo 2015.

Aarẹ Buhari sọ ọrọ yii nibi ifilọlẹ iwe Jonathan ti o pe orukọ rẹ ni "My Transition Hours" ni Abuja.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ààrẹ àná orílẹ́-èdè Nàìjírìa, Goodluck Jonathan sọ nínú ìwé rẹ̀ pé Barack Obama ló ṣokùnfà ìjákulẹ̀ òun nínú ìdìbò ọdun 2015

O ni oloselu ijọba awa-ara-wa tootọ, to si sọwọn ni aarẹ ana Jonathan.

Aarẹ Buhari wa fikun wi pe Jonathan yoo pada goke agba nitori iwa irẹlẹ to wu lasiko idibo ọdun 2015 naa ti mu ki ọpọ eniyan nilẹ adunlawo ati ni okeere lati fẹran rẹ.

Jonathan: Kò ṣẹ̀yìn Obama bí mo ṣe fìdírẹmi nínú ìdìbò 2015

Aarẹ ana lorilẹ-ede Naijiria, Goodluck Jonathan ti sọ pe, Aarẹ ilẹ Amẹrika tẹlẹ, Barack Obama lo ṣagbatẹru bi oun ṣe fidirẹmi ninu idibo aarẹ ọdun 2015.

Aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Jonathan ti o n ṣe ọjọ ibi rẹ f'ẹsun kan Obama pe o ṣegbe lẹyin ẹgbẹ osẹlu alatako lẹyin to fi fidio kan ranṣẹ si awọn Naijiria nibi ti o ti rọ wọn lori oludije to yẹ ki wọn dibo wọn fun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ ana, Goodluck Jonathan sọrọ lori idibo ọdun 2015

Ọmọwe Jonathan sọrọ naa ninu iwe rẹ to pe ni ''My Transition Hours'' to ṣe ifilọlẹ rẹ nilu Abuja lọjọ Iṣẹgun. O ṣe ifilọlẹ iwe naa pẹlu ayẹyẹ ọdun mọkanlelọgọta lori oke eepẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Jonathan fikun ọrọ pe, Obama sọ fun awọn ọmọ Naijiria lati ṣi abala tuntun ninu eto osẹlu Naijiria pẹlu ibo wọn.

O ni itumọ ọrọ naa ni pe Obama n sọ fun awọn ọmọ Naijiria lati dibo fun ẹgbẹ alatako ki wọn si bẹrẹ ijọba tuntun.

Jonathan fidi rẹmi ninu idibo aarẹ ọdun 2015 nibi ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti jawe olubori.

Iyẹn ni igba akọkọ ti ti aarẹ to wa lori aleefa lorilẹ-ede Naijiria yoo fidirẹmi lati wọle lẹẹkeji.

Jonathan fi iwe naa ṣalaye awọn igbesẹ to gbe lasiko to n ṣe ijọba Naijiria ati awọn nkan mii to ṣẹlẹ ti ọpọ ko mo lasiko naa.

Jonathan: Cambridge Analytica ko sisẹ fun mi

Aarẹ ana lorilẹ-ede Naijiria, Goodluck Jonathan ti sọ pe, oun ko fi igba kankan bẹ ileesẹ Cambridge Analytica lọwẹ lati da si ipolongo rẹ fun idbo ọdun 2015.

Ni ọjọọru ni iwe iroyin kan ni ilẹ Gẹẹsi gbe iroyin sita wi pe ọkan lara awọn baba olowo to satilẹyin fun ipolongo ibo aarẹ ana lorilẹ-ede Naijiria, Ọmọwe Goodluck Jonathan gbe isẹ fun ileesẹ asewadi ijinlẹ naa eleyi to n foju wina titapa sofin aabo ẹtọ ọmọniyan bayii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wọn fi ẹsun kan Cambridge Analytical pe o lọwọ ninu ipolongo ibo fun Jonathan

Wọn fi ẹsun kan ileesẹ Cambridge Analytica pe wọn gbe isẹ naa fun wọn lati wa awọn iroyin kọlọfin ti yoo se akoba funoludije alatako nigbanaa, Muhammadu Buhari.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ààrẹ àná orílẹ́-èdè Nàìjírìa, Goodluck Jonathan sọ nínú ìwé rẹ̀ pé Barack Obama ló ṣokùnfà ìjákulẹ̀ òun nínú ìdìbò ọdun 2015

Amọ agbẹnusọ tẹlẹ fun Aarẹ Jonathan, Rueben Abati salaye ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC wi pe, ko si ohun to jọọ, nitori lasiko ti ipolongo ibo waye, tipẹtipẹ bayi loun sunmọ Ọmọwe Goodluck Jonathan, ko si si igba kan ti ileesẹ ipolongo ibo rẹ daa laba tabi gbaa lero lati gbe iru igbesẹ bẹẹ.

Ọgbẹni Abati ni, ọpọ awọn eeyan ni wọn se eto ipolongo adase lati satilẹyin fun aarẹ nigbanaa, Goodluck Jonathan, lai jẹ wipe o han si aarẹ Jonathan oun ti wọn n se.

Àkọlé fídíò,

'Lórí ìgbéyàwó mi, ẹ̀ ṣáà jẹ́ kó wà báyìí'

Gẹgẹ bii iwe iroyin ilẹ Gẹẹsi kan, the Guardian se sọ, Cambridge Analytica lo wa lẹyin ipolongo kan to sọ wi pe, bi Buhari ba lee wọle sipo aarẹ lorilẹ-ede Naijiria lọdun 2015, yoo se amulo ofin ẹsin Islam ati Sharia jakejado orilẹede Naijiria.

Ileesẹ SCL Elections to ni Cambridge Analytica, fidi rẹ mulẹ wi pe, wọn bẹ awọn lọwẹ lati se atilẹyin fun ipolongo ibo Ọmọwe Jonathan nigba naa, sugbọn wọn yannana rẹ wipe ipolongo ati ipolowo ọja ni wọn se.