Ikọ ọmọogun ajọ UN n kuro lorilẹede Liberia

Awọn osisẹ ajọ UN kan joko Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ipenija ọrọ aje ati eto abo ti ko tii fẹsẹrinlẹ daadaa jẹ ara ipenija ti liberia lee koju

Igbakeji akọwe agba ajọ isọkan agbaye, to tun ti figbakanri jẹ minisita fọrọ ayika tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Arabinrin Amina Mohammed ti gunlẹ si orilẹede Liberia ni igbaradi fun ayẹyẹ fifopin si isẹ ikọ ọmọogun apẹtusaawọ ti ajs isọkan agbaye fi sọwọ si orilẹede naa.

Ni ọdun 2003 lawọn ọmọogun apẹtusija latọdọ ajọ isọkan agbaye gunlẹ si orilẹede Liberia lati gba nkan ija ogun lọwọ ogunlọgọ awọn to ja ogun abẹle lorilẹede naa saaju eto idibo akọkọ to waye lọdun 2005 lẹyin ogun abẹle orilẹede naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọdun mọarundinlogun lawọn ikọ apẹtusija ajọ UN ti lo lorilẹede Liberia

Igbesẹ yii n waye nigba ti o n lọ si osu meji ti ijọba tuntun lorilẹede Liberia labẹ Aarẹ George Weah n bẹrẹ isẹ.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, Igbakeji akọwe agba ajọ isọkan agbaye Arabinrin Amina Mohammed ni ọrọ ọhun kii se nipa pe ikọ apẹtusija ajọ isọkan agbaye n ko kuro ni orilẹede naa bikose wi pe alaafia ti de si orilẹede Liberia eleyi to jẹ idunnu ajọ isọkan agbaye.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajọ UN ni asiko to fun orilẹede Liberia se amojuto ipilẹ ọjọ ọla wọn

"Ohun kan to se pataki ni wi pe alaafia ati jọba lorilẹede Liberia eleyi to yẹ ki awọn eeyan gbogbo ti ọrọ kan o lee fi sa ipa ki a maa pada si inu wahala atẹyinwa mọ nitori a ti se ifọwọsowọpọ pẹlawọn asaaju nigbanaa lati se ifilọlẹ alaafia lorilẹede Naijiria."

Arabinrin Mohammed ni pẹlu ipenija ọrọ aje, idaleesẹ silẹ ti ko duro deede ati ileesẹ ọlọpa ti ko to nkan niye, oni kiko awọn ikọ ọmọogun ajọ isọkan agbaye kuro lorilẹede Liberia kiise ohun ti yoo da orilẹede naa laamu bikose eyi ti yoo fun awọn eeyan ibẹ ni igbẹkẹle ati ọkan akin tuntun lati da duro ninu igbẹkẹle isere orilẹede naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: