Awọn dokita iṣegun Naijiria n kerora lori ẹka ilera

Dokita isegin kan dọwọboju Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn dokita iṣegun Naijiria n kerora lori ẹka ilera

Ni ọjọọbọ ni gbajugbaja oludokoowo ni, Ọgbẹni Bill Gate na ijọba apapọ orilẹede Naijiria ni pasan ọrọ wi pe ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ko se e to lẹka eto ọrọ aje, ẹkọ ati ilera.

Nipataki julọ ọgbẹni Gate ni eto ilera alabọde si ku diẹ kaato eleyi to ni o n ṣokunfa iku ọwọọwọ laarin awọn ewe lorilẹede Naijiria.

Ki Gate to sọrọ rẹ lawọn eeyan kaakiri orilẹede Naijiria ati loke okun ti n pariwo pe nkan o ṣe deede lẹka eto ilera lorilẹede Naijiria.

Image copyright @nmanigeria
Àkọlé àwòrán Eto ilera alabde ti di ma-kan fun p m orilede Naijiria

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, akọwe agba fun ẹgbẹ awọn dokita isegun oyinbo lorilẹede Naijiria, NMA, Dokita Yusuf Tanko Sununu ṣalaye wi pe lootọ ni ẹka ilera alabọde nilo amojuto gidigidi.

Ẹgbẹ awọn dokita iṣegun oyinbo lorilẹede Naijiria ni lọwọ yii iye ti ijọba apapọ n ya sọtọ ni eto isuna rẹ fun eto ilera kere jọjọ, eyi si n se akoba fun idagbasoke ẹka yii, paapaa julọ eto ilera alabọde.

Image copyright @nmanigeria
Àkọlé àwòrán Owo ti ijọba apapọ n la kalẹ labẹ eto isuna ko to iye ti ajọ isọkan agbaye la kalẹ

"Ti a ba n sọrọ eto ilera alabọde lorilẹede Naijiria, gbogbo awọn araalu ti wọn n lo eto ilera alabọde ni wọn n na owo gbẹmigbẹmi lati lanfani itọju, eleyi ti kii kuna to lẹyin-o-rẹyin."

Ẹgbẹ NMA ni asiko to fun ijọba apapọ lati jara mọ agbekalẹ eto ilera tẹru-tọmọ, Universal health coverage, ki eto ilera lee jẹ eyi ti yoo wa larọwọto gbogbo eniyan lorilẹede Naijiria.

Lẹka ipinlẹ, ko si iyatọ lori ọrọ naa pẹlu bi awọn alamojuto ilera ni ipinlẹ pẹlu se n sọ wi pe ọsan ko so didun lẹka naa.

Image copyright @nmanigeria
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ NMA ni asiko to fun ijọba apapọ lati jara mọ agbekalẹ eto ilera tẹru-tọmọ, Universal health coverage

Alaga ẹgbẹ dokita isegun oyinbo, NMA ni ipinlẹ Kwara, Dokita Kunle Ọlawepo salaye wi pe lẹyin Ọjọgbọn Olukoye Ransome-Kuti to sa ipa ribiribi fun idagbasoke ẹka ilera alabọde lasiko to fi jẹ minisita feto ilera, ko si ijọba to tun gbe ọwọ idagbasoke lẹka eto ilera alabọde soke mọ.

"Kii se eto ilera alabọde nikan ni ko gbadun lorilẹede Naijiria, sugbọn ti ilera gbogbo.

"Gbogbo awọn osisẹ to yẹ ko wa lẹka eto ilera gan an ni wọn ti salọ tan.

"Ko si awọn ohun elo lawọn ileewosan alabọde, bẹẹni isẹ wọn gan ko rinlẹ laawujọ."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: