Dapchi: Baba akẹkọ Dapchi to ku ni o san ko wa lahamọ

Buhari ya fọto pẹlu awọn akẹkọ naa Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari seleri lati se awari akẹkọ Dapchi kan to ku lahamọ Boko haram

Baba akẹkọbinrin kan soso to ku lara awọn ti wọn ji gbe nilu Dapchi, Sharibu Lathan ti ransẹ si ọmọ rẹ wi pe o san fun un ki wọn pa a ju ki o fi ẹsin kristẹni silẹ to ba jẹ wi pe eleyi ni awọn ikọ Boko haram naa ko fi ni tu u silẹ.

Iroyin sọ wi pe iks adukukulaja Boko haram ks lati fi ọmọdebinrin naa silẹ nigba to faake kọri wi pe oun ko ni fi ẹsin kristẹni ti oun n se silẹ lati gba ẹsin islam gẹgẹbii awọn onisẹẹbi naa se n fẹ.

Sharibu Lathan to jẹ ọlọpa abẹle kan lagbegbe naa faake kọri o wi pe inu oun dun de isalẹ ikun wi pe smọ oun ks lati yipada si ẹsin Islam.

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Lọjọọru ni wọn tu awọn akẹkọ naa silẹ

O ni lootọ o ya oun lẹnu wi pe ọmọbinrin oun lee ni ipinnu bẹẹ nitori kii sọrọ bẹẹni ibi ti wọn ba ni ko tẹ si naa nii maa n tẹ si.

Ọgbẹni Sharibu Lathan wa rọ ọmọ rẹ lati duro pẹlu skan akin bi o ti lee wu ki wọn fi iya jẹẹ to.

O seleri wi pe bi wọn ba lee tu ọmọbinrin oun silẹ oun yoo daa pada si ileewe pẹlu bi awọn ikọ Boko haram naa ti se kilọ pe awọn yoo pada tun wa ji ẹnikẹni to ba pada lọ si ileewe girama ilu Dapchi naa gbe pada ni.

Aarẹ Buhari gbalejo awọn akẹkọ Dapchi nileejọba nilu Abuja

Amọsa aarẹ Muhammadu Buhari ti gbalejo awọn akẹkọ ti ikọ Boko haram da pada lọjọọru nilu Abuja.

Nibi ipade naa ni Aarẹ Buhari ti fi to awọn akẹkọbinrin naa leti wi pe ki wọn tẹsiwaju pẹlu ala rere wọn lati kẹkọ gboye laisi ifoya.

Aarẹ Buhari wa pasẹ fun awọn ileesẹ alaabo gbogbo lati rii pe aabo to daju wa lawọn ileewe gbogbo.

Bakanna lo tun fi da awọn obi akẹkọ ilu Chibok to ku loju wi pe ki wọn maa se sọ ireti nu atipe ijọba n sisẹ lati rii pe awọn ọmọ tiwọn pẹlu pada.