Ileesẹ Ọlọpa: A ti so ofin ko si ọlọpa fun eekan‘lu rọ

Ibrahim Idris, Ọga Ọlọpa Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O ti pẹ ti wọn ti n paṣẹ pe ki wọn o yọ ẹṣọ ọlọpa kuro lẹyin awọn eeyan pataki

Ọga ọlọpa Naijiria, Ibrahim Idris, ti so aṣẹ yiyọ awọn ọlọpa to n sisẹ ẹsọ kuro lẹyin awọn ọlọla ilu lẹyin rọ na, lẹyin ọjọ kan to kede aṣẹ naa.

Ọga ọlọpa ọhun ni, aṣẹ naa yoo di mimuṣẹ lati ogunjọ osu kẹrin ọdun 2018.

Nigba to n s'alaye nkan to faa ti ọga ọlọpa fi ṣe bẹẹ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa, Jimoh Moshood, sọ wipe ileesẹ ọlọpa gbe igbesẹ naa lati s'ayewo iye awọn ọlọpa to wa n ta.

O ni, igbese naa yoo fun ileesẹ ọlọpa l'anfaani ati mọ awọn ọlọpa ti wọn n ṣọ awọn eeyan pataki laarin ilu boti tọ ati boti yẹ.