Kunle Ọlajide: Ariwa lo n fa Naijiria sẹyin

Dokita Kunle Ọlajide Image copyright Kunle Ọlajide
Àkọlé àwòrán Ibrahim Coomassie sọ wi pe Naijiria ko le s'ẹmi laisi ariwa

Ẹgbẹ igbimọ agba Yorùbá, ti wọn mọ si Yorùbá Council of Elders lede Gẹẹsi, (YCE) ti sọ wi pe ẹkun ariwa Naijiria ni isoro to n fa orilẹede naa sẹyin.

Akọwe agba fun ẹgbẹ naa, dokita Kunle Ọlajide, lo sọ eleyi lẹyin igba ti alaga ẹgbẹ awọn eeyan ẹkun ariwa orilẹede naa, Ibrahim Coomassie, sọ wi pe Naijiria ko le s'ẹmi laisi ariwa.

Lẹnu ijọ mẹta yii ni Ibrahim Coomassie sọ wi pe Naijiria ko le s'ẹmi laisi ariwa.

Ṣugbọn ẹgbẹ igbimọ agba Yorùbá wi pe Naijiria nilo atunto nitori ki gbogbo agbegbe orilẹede naa maa lo nnkan to ni fun awọn eeyan rẹ.

Dokita Kunle sọ wi pe atunto Naijiria ko ni f'aye gba ki gomina tabi ijọba ipinlẹ ni iru agbara kiku-yiye ti awọn gomina ni lasiko yii.

O s'afikun wi pe atunto lole mu idẹra ba mẹkunu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ tẹti si ọrọ ti dokita Kule Ọlajide sọ nipa nnkan ti alaga ẹgbẹ ariwa sọ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: