Irinajo Libya: Ọmọ Naijiria mọ́kàndínláàdọ́jọ pada sile

Awon arinrinajo omo Naijiria lati Libya Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọmọ Naijiria mọ́kàndínláàdọ́jọ pada sile lati Libya

Ile-iṣẹ to n risi iṣẹlẹ pajawiri ni orile-ede Naijiria (Nema) ti tẹwọ gbamọ orilẹede Naijiria arinrinajo mọ́kàndínláàdọ́jọ lẹyin ti wọn ronu lati pada wa sile lati orilẹede Libya.

Wọn pada de si papakọ ofuurufu ti Murtala Muhammed nilu Eko lalẹ ọjọbọ pẹlu ọkọ ofuurufu Buraq Airline ti nọmba jẹ 5A-DMG.

Ọkọ ofuurufu naa balẹ ni deede agogo mọkanla ku iṣẹju mẹẹdogun.

Atẹjade kan lati ọwọ oludari ajọ naa ni ẹka ti ipinlẹ Eko, ọgbẹni Yakubu Suleiman sọ wipe awọn ọkunrin mẹ́tàdínláàdọ́fà ati awọn obinrin méjílélógójì lo pada wa sile.

Image copyright @abikedabiri
Àkọlé àwòrán Ọmọ Naijiria mejilelaadoje pada sile lati Libya loṣu kinni ọdun

Ogunlọgọ awọn atipo ọmọ orilẹede Naijiria ni wọn ti npada wale lati orilẹede Libya lẹyin awuyewuye lori ọrọ ifeniyan dokoowo ati ifiyajẹni ni orilẹede naa.

Ọmọ Naijiria toto ẹgberun mefa ati egberin ole mefa (6,806) lo ti pada sile bayi lati orilẹede Libya. Tẹẹ ba gbagbe, Ojilelẹẹdegbẹta ọmọ Naijiria, to jẹ isi kinni awọn ọmọ Naijiria to rinrin ajo lọ silẹ Libya, lo pada de si ilu Port Harcourt ni oṣu kinni ọ̀dun yi.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: