Ina jo ọja binukonu lọjọta nipinlẹ Eko

Ọja binukonu
Àkọlé àwòrán Ina jo ọja binukonu lọjọta nipinlẹ Eko

Ọpọlọpọ kudia ati ohun ini lo ti ṣegbe ninu ibugbamu ina to ṣẹlẹ ni ọja Binukonu nilu Ojota nipinlẹ Eko lowurọ ọjọ ẹti.

Eyi ni ẹlẹẹkẹta ti ina yoo jo ọja yii laarin ọdun mẹta. Ọja Binukonu jamba ina ni ọdun 2015 ati ni oṣu kọkanla ni ọdun 2017.

Awọn alẹnulọrọ sọ fun ileeṣẹ BBC wipe iṣẹlẹ ina yii ṣadeede bẹrẹ ni agogo kan abọ oru ti o si jo awọn ile itaja (ṣọọbu) ti o to aadọta patapata.

Àkọlé àwòrán Eyi ni ẹlẹẹkẹta ti ina yoo jo ọja Binukonu lẹyin ti ọdun 2015 ati 2017.

Awọn onisowo gbìyànjú lati ṣaajo awọn ọja wọn lati ko wọn kuro ninu awọn ile itaja wọn ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.

Alhaja Rehanat Salami, Obinrin oludari ọja naa (Iyalọja) sọ pe ina mọnamọna ijọba lo ṣe okunfa ijamba ina naa.

O sọ pe, "Mi o wo agogo nigbati mo gba ipe wipe ọja wa n jona ti mo si yara jade wa si ọja.

Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ kudia ati ohun ini lo ti ṣegbe ninu ibugbamu ina to ṣẹlẹ ni ọja Binukonu

"Nigbati iṣẹlẹ ina yi waye lẹẹmeji sẹyin, a ṣe gbogbo ohun ti ijọba paṣẹ fun wa lati ṣe.

"Nigbati iṣẹlẹ ina yi waye ni igba akọkọ, ijọba ṣe iranlọwọ fun wa lati tun awọn ile itaja wa kọ fun wa laigbowo.

Àkọlé àwòrán Won so pe ina mọnamọna ijọba lo ṣe okunfa ijamba ina naa

"Mo gbọ pe ina mọnamọna lo fa ijamba yi, mo ti kìlọ fun gbogbo awọn ọlọja lati ma pa awọn ina ninu ṣọọbu wọn ti wọn ba ti taja tan ki wọn too lọ si ile wọn.

"A maa nrii daju pe a pa gbogbo awọn ina mọnamọna ni oja ki a too lọ."

Akọwe ọja naa, ọgbẹni Gbenga Fayemi sọ pe awọn oludari ọja naa ti ṣe ipese awsn ohun idaabo bo awọn ọja nibẹ lati igba ti iṣẹlẹ ina ti waye nigbakan ri.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: