Ijinigbe Dapchi: Bo ṣe ṣẹlẹ

Awọn akẹẹkọbinrin Dapchi mẹrindinlaadofa ati ọmọdekunrin kan ti ṣepade pọ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni Abuja to jẹ olu-ilu Naijiria.

Ewọ akojọpọ iroyin bii wọn ṣe ji awọn ọmọ Dapchi naa gbe titi di ọjọ ti mẹrindinlaadofa (106) fi gba itusilẹ.

Ọdun 2018

 • Ọjọ 19, Osu Keji

  Awọn afunrasi ikọ agbẹsunmọmi Boko Haram se ikọlu si ile-ẹkọ Girama fun awọn obinrin ni ilu Dapchi, nipinlẹ Yobe, ni ila-ariwa orilẹede Naijiria.

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 20, Osu Keji

  Ijọba orilẹede Naijiria fi idi rẹ mulẹ wipe aadọfa awọn ọmọbinrin Dapchi lo sọnu

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 21, Osu Keji

  Ijọba ipinlẹ Yobe kede wipe awọn ọmọogun Naijiria ti gba lara awọn ọmọ naa silẹ atiwipe wọn wa lọdọ ikọ awọn ọmọogun naa.

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 22, Osu Keji

  Ijọba ipinlẹ Yobe sọwipe awọn o sọ bẹẹ mọ, wọn si bere fun idariji nitoriwipe kosi ọmọ kankan ti wọn gba la.

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 23, Osu Keji

  Aarẹ Muhammadu Buhari pe ijinigbe awọn ọmọbinrin Dapchi ni "isẹlẹ pajawiri gbogboogbo".

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 25, Osu Keji

  Ile-ise omoogun ofurufu lorilẹede Naijiria sọwipe awọn ti ran ikọ awọn lati lọ wa awọn ọmọ naa lawari.

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 26, Osu Keji

  Ile-isẹ ọmọogun Naijiria sọwipe kosi ootọ ninu ọrọ ti Ijọba ipinlẹ Yobe sọ nipa kiko awọn ọmọogun kuro ni oju poopo lọjọ ti isẹlẹ naa sẹlẹ. Amọ, wọn sowipe lootọ ni wọn kọ awọn ọmọogun kuro nibe nitoriwipe awọn ri wipe alaafia ti jọba lagbeegbe naa.

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 27, Osu Keji

  Ijọba orilẹede Naijiria bẹrẹ iwadii lori bi isẹlẹ ijinigbe awọn akẹẹkọ aadọfa se sọnu.

 • Ọjọ 28, Osu Keji

  Akowe gbogboogbo fun Ajọ Agbaye (UN), Antonio Guterres bu ẹnu atẹ lu ijinigbe awon ọmọ Dapchi naa.

 • Ọjọ 2, Osu Kẹta

  Ajafẹtọ ọmọeniyan kan lorilẹede Naijiria ti orukọ rẹ njẹ, Aisha Wakil, ti awọn eniyan mọ si "Mama Boko Haram" nitoripe o mọ lara awọn ikọ Boko Haram naa nigba ti wọn wa ni kekere, sọ fun awọn oniroyin wipe igun Barnawi sọ fun oun wipe awọn lawọn ji awọn akẹẹkọ naa gbe.

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 9, Osu Kẹta

  Awọn Obinrin wọde ni Abuja lati fi aidunnu wọn han lẹyin osẹ mẹta ti wọn ti ji awọn ọmọ naa gbe.

 • Ọjọ 12, Osu Kẹta

  Aarẹ Muhammadu Buhari kede wipe awọn yoo fọrọwerọ lori bii awọn ajinigbe naa yoo se fi awọn ọmọ naa silẹ lai lo ipa.

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 14, Osu Kẹta

  Aare Muhammadu Buhari gbera lọ si Dapchi lati lọ tu awọn obi awọn ọmọ naa ninu, atiwipe ijọba yoo doola ẹmi awọn akẹẹkọ naa.

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 20, Osu Kẹta

  Ajọ Amnesty International sowipe ijọba orilẹede Naijiria ko kọbi ara si ikilọ wipe awọn ikọ Boko Haram fẹ se ikọlu si ilu Dapchi ni wakati diẹ si igba ti awọn ẹsinokọku naa wa ji awọn ọmọbinrin naa gbe.

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi

 • Ọjọ 21,Osu Kẹta

  Ijọba orilẹede Naijiria se kede wipe mẹrinlelọgọrun(104) ninu aadọfa (110) awọn akẹẹkọ Dapchi ni awọn ajinigbe ti tu silẹ.

  Ẹka ẹkunrẹrẹ rẹ nibi