Spain: Ọwọ ọlọpa tẹ gbajugbaja DJ lati Naijiria to n ṣowo nọbi

Awọn olowo naabi duro si ẹgbẹ ọkọ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Europol ni ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ wa kakari agbaye

Awọn ọlọpa lorilẹede Spain ti doola ẹmi awọn obinrin to jẹ ọdọ langba mọkandinlogoji (39) ati awọn ọmọdebinrin ti won gba ọna ẹburu wọ orilẹede Spain fun isẹ naabi gba ọwọ egbe okunkun kan lorilẹede Naijiria.

Ajọ ọlọpa Europol sọwipe awọn ti fi panpẹ ọba mu eniyan mọkandinlaadọrun, to jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiye, ti ọkan lara awọn afunrasi naa si jẹ gbajugbaja alasopọ orin igbalode(DeeJay) to pada lọ si orilẹede Spain lẹyin to se fidio orin kan, wa lara awọn to n fi awọn obinrin lati orilẹede Naijiria sowo naabi lorilẹede Spain, Ilẹ Gẹẹsi ati Libya.

Iwadii fihan wipe awọn to n fini sowo naabi naa ko awọn eniyan si inu ihọ ilẹ to jẹ ibi irira, ti wọn si tun dunkoko mọ wọn pẹlu ooguin abẹnugọngọ.

Wọn fikun wipe awọn ẹgbẹ eiye to jẹ ẹgbẹ okunkun lorilẹede Naijiria n fi awọn obinrin naa sowo naabi lati le san gbese to to billionu mẹtala naira ($37,000; £26,000) ti wọn jẹ.

Europol sọwipe awọn bere iwadii pelu iranwọ awọn ọlọpa lati Orilẹede Gẹẹsi ati Naijiria, lẹyin ti ọmọdebinrin kan fi ẹjọ sun awọn ọlọpa wipe awọn eniyan kan fi tipatipa mu oun wa si orilẹede Spain lati wa se isẹ naabi pẹlu idukokomọni.

Iwadii fihan wipe ẹgbẹ okunkun Ẹiye naa ni igun lorisirisi si awọn orilẹede to wa ni Europe, Africa ati Middle East, ti wọn si n sisẹ kaakiri agbaye pẹlu owo ribiribi ti wọn n fi si ile ifowopamọ lokeere ati lorilẹede Naijiria.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: