Koko iroyin: Ijamba ina l’Eko, DJ Naijiria to n ṣowo nọbi ni Spain

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.

'Ọpọlọpọ ohun ini segbe ni ijamba ina l’Ọjọta'

Àkọlé àwòrán,

Ina jo ọja binukonu lọjọta nipinlẹ Eko

Ọpọlọpọ kudia ati ohun ini lo ti ṣegbe ninu ibugbamu ina to ṣẹlẹ ni ọja Binukonu nilu Ojota nipinlẹ Eko lowurọ ọjọ ẹti.

Eyi ni ẹlẹẹkẹta ti ina yoo jo ọja yii laarin ọdun mẹta. Ọja Binukonu jamba ina ni ọdun 2015 ati ni oṣu kọkanla ni ọdun 2017. E wo ibi fun ẹkunrẹrẹ.

Gomina ipinlẹ Ondo kuna ni ile ẹjọ to gajulọ

Ileẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria ti da ẹjọ kotẹmilọrun ti Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu gbe wa siwaju rẹ nu pẹlu alaye pe ko lẹsẹ-n-lẹ.

Olusẹgun Abraham, to baa du ipo asia gomina ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ondo, lo pee lẹjọ.

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Fidio wa fun toni

"Awọn panapana ni awọn ko lomi nigba ti awọn eniyan pe fun iranwọ nibi ijamba ina to sọ l’ọja Ọjọta"

Àkọlé fídíò,

Ina jo ọja binukonu lọjọta