Ẹsa awọn aworan to rẹwaju kaakiri Arfika l'ọsẹ yii

Ẹsa awọn aworan to rẹwaju kaakiri Afrika ati ti awọn eeyan Afrika nibomiran lagbaye ninu ọsẹ yii.

Awọn ọmọ kan ni ibudo awọn atipo kan ni Kalemie l'orilẹede Ijọba-ara-ẹni ti Congo Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ kekere ilẹ Congo kan ni ibudo awọn atipo ni Kalemie to wa ni orilẹede Ijọba-ara-ẹni Congo. Ogun ẹlẹyamẹya kan to n lọ lọwọ ti le awọn eeyan mẹtadinlaadọrin (67) kuro ni ibugbe wọn l'agbegbe naa
arẹwa awọsọta Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Awọn arẹwa awọsọta n s'afihan asọ ti ọmọ ilẹ South Africa, Gavin Rajah, ran nigba ọsẹ ayẹyẹ aṣọ ọṣọ Afrika nigboro Cape Town, lorilẹede South Africa
Ọkunrin kan n tun opo ṣe lori ọkọjuomi to n gbe awọn arinajo kan lọ nirolẹ ni eti odo to wa ni erekusu Lamu, to jẹ ibugbafẹ to gbajumọ ni orilẹede Kenya. Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Ọkunrin kan n tun opo ṣe lori ọkọjuomi to n gbe awọn arinajo kan lọ nirolẹ ni eti odo to wa ni erekusu Lamu, to jẹ ibugbafẹ to gbajumọ ni orilẹede Kenya.
Agbo kan wọ ami ẹyẹ to jẹ nigba ti wọn lu gbajo ọlọjọ mẹta ni Misrata, Libya. Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Agbo kan wọ ami ẹyẹ to jẹ nigba ti wọn n lu gbanjo ọlọjọ mẹta ni Misrata, Libya.
Diẹ ninu awọn akẹkọbirin Dapchi nigba ti wọn fẹ wọ baalu nibudo awọn ologun ofurufu ni Maiduguri, Nigeria. Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Diẹ ninu awọn akẹkọbirin Dapchi nigba ti wọn fẹ wọ baalu nibudo awọn ologun ofurufu ni Maiduguri, Nigeria. Awọn oṣiṣẹ ijọba Naijiria sọ wipe awọn akẹkọbirin maarundinlaadọfa ati ọmọkunrin kan ni Boko Haram tu silẹ, sugbọn iroyin ṣọ wipe maarun ninu wọn ti ku.
Wanaume kadhaa wakiingia kwenye Lori wakiwa na mizigo yao, waliachiwa kwa msamaha wa Rais wa Burundi. Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn ti wọn s'ẹwọn tẹlẹ ri, wọn fẹ gun ọkọ nla kan lati ọgba ẹwọn Mpimba l'abala kan ninu aforoji ti aarẹ fun awọn ẹlẹwọn pipọ kaakiri, ni Bujumbura, Burundi.
Awọn aarẹ Afrika duro ya aworan nigba ipade ajọ isọkan Afrika lati se agbekalẹ ibudo kara-kata ọfẹ ni Kigali, ilẹ Rwanda l'Ọjọru eleyi ti yoo jẹ ọkan lara awọn ibudo kara-kata ọfẹ to tobi ju l'agbaye. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn aarẹ Afrika duro ya aworan nigba ipade ajọ isọkan Afrika lati se agbekalẹ ibudo kara-kata ọfẹ ni Kigali, ilẹ Rwanda l'Ọjọru eleyi ti yoo jẹ ọkan lara awọn ibudo kara-kata ọfẹ to tobi ju l'agbaye. Awọn orilẹede mẹwa, t'oun ti orilẹede ti ọrọaje rẹ gbooro ju l'Afrika, Naijiria, wọn kọ jalẹ lati f'ọwọ si eto naa nitori ibẹru pe ole la iṣẹ lọ.
Mashabiki wa Sfax wakiwa wamewasha moto wakati wa mechi ya kirafiki dhidi ya wachezaji wa zamani wa kimataifa wa Ufaransa, kuadhimisha miaka 90 ya Timu hiyo ya Tunisia Image copyright BBC Sport
Àkọlé àwòrán Awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Sfax n fi ina ṣere nigba ifẹwọnsẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa pẹlu awọn agbabọọlu ilẹ Faranse ana lati ṣe ayẹyẹ aadọrun ọdun ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Tunisia naa ni papa-isere Mhiri in Sfax
Afin to kọkọ gba ami ẹyẹ obirin to rẹwa ju ni Zimbabwe, Sithmbiso Mutukura gba ododo lẹyin igba ti wọn de l'ade ni Harare. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Afin to kọkọ gba ami ẹyẹ obirin to rẹwa ju ni Zimbabwe, Sithmbiso Mutukura, gba ododo lẹyin igba ti wọn de l'ade ni Harare. Ẹni ọdun mejilelogun ọhun bori awọn eeyan mejila ọtọtọ nibi idije arẹwa afin akọkọ ti wọn se lati din oju yẹpẹrẹ ti awọn eeyan n fi n wo awọn afin ku.
Mashabiki wa Sfax wakiwa wamewasha moto wakati wa mechi ya kirafiki dhidi ya wachezaji wa zamani wa kimataifa wa Ufaransa, kuadhimisha miaka 90 ya Timu hiyo ya Tunisia Image copyright BBC Sport
Àkọlé àwòrán Awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Sfax n fi ina ṣere nigba ifẹwọnsẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa pẹlu awọn agbabọọlu ilẹ Faranse ana lati ṣe ayẹyẹ aadọrun ọdun ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Tunisia naa ni papa-isere Mhiri in Sfax
Ọdọmọdekunrin apẹja ni Congo n tun awọn rẹ se ni eti omi-adagun Tanganyika ni Kalemie, ni orilẹede Ijọba-ara-ẹni Congo Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọdọmọdekunrin apẹja ni Congo n tun awọn rẹ se ni eti omi-adagun Tanganyika ni Kalemie, ni orilẹede Ijọba-ara-ẹni Congo
Nnkan ti iji Eliakim sọ aye da l'ẹgbẹ Manambonitra ni Madagascar, l'ọjọ Abamẹta. Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Nnkan ti iji Eliakim sọ aye da l'ẹgbẹ Manambonitra ni Madagascar, l'ọjọ Abamẹta.
Obirin kan n da omi ẹrọ sinu garawa ni Abidjan, l'Ọjọru (Wednesday) nigba ti ọjọ ayẹyẹ omi agbaye ku ọla. Akọle ọjọ na l'ọdun 2018 ni "Ẹda fun Omi", titọ ọna abayọ isẹda fun awọn ipenija omi ti o n koju wa l'ode oni. Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Obirin kan n da omi ẹrọ sinu garawa ni Abidjan, l'Ọjọru (Wednesday) nigba ti ọjọ ayẹyẹ omi agbaye ku ọla. Akọle ayẹyẹ na l'ọdun 2018 ni "Ẹda fun Omi", titọ ọna abayọ iṣẹda fun awọn ipenija omi ti o n koju wa l'ode oni.
Alufa orilẹede South Sudan kan n dari ijọsin ni ibudo atipo kan to wa ni ilu Obo l'orilẹede Central African Republic l'ọjọ Ẹti. Lati ọdun 2016, ni awọn alasala ti wọn le ni ẹgbẹrun meji ti sa wọ orilẹede naa. Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Alufa orilẹede South Sudan kan n dari ijọsin ni ibudo atipo kan to wa ni ilu Obo l'orilẹede Central African Republic l'ọjọ Ẹti. Lati ọdun 2016, ni awọn alasala ti wọn le ni ẹgbẹrun meji ti sa wọ orilẹede naa.

Orisun awọn aworan naa ni AFP, Reuters, EPA ati Getty Images

Ní àyíká BBC