Ikọlu Dapchi: Awọn akẹkọ pada sile lẹyin ipade pẹlu Buhari

Awọn akẹkọ n wọ baluu ileesẹ ọmọogun ofurufu Image copyright Nigeria Airforce
Àkọlé àwòrán Awọn ikọ ọmọogun ilẹ Naijiria lo sin wọn dele

O le ni ọgọrun awọn akẹkọbinrin Dapchi ti awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram da pada, ti awọn ologun orilẹede Naijiria ti da pada sọdọ awọn obi wọn bayii ni ilu Dapchi.

Ni nkan bii osu kan sẹyin, ni lawọn ikọ Boko Haram ji awọn akẹkọ yii gbe nilu Dapchi nipinlẹ Yobe to wa lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Nkan bii aago kan abọ ọsan ọjọ aiku lawọn akẹkọ naa gunlẹ silu dapchi ninu ọkọ bọọsi marun, ti awọn ologun si kọwọrin pẹlu wọn.

Image copyright Nigeria Airforce
Àkọlé àwòrán Awọn eeyan ilu Dapchi fi ijo atayọ pade awọn akẹkọ naa

Ayọ ati inu didun lawọn araalu Dapchi, paapaa julọ awọn obi awọn ọmọ naa, fi pade wọn.

Lẹyin ti awọn ikọ Boko Haram tu awọn akẹkọ naa silẹ lọsẹ to kọja, ti wọn si foju kan awọn obi wọn, ni wọn tẹkọ leti lọ silu Abuja nibi ti wọn ti fojurinju pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari.

Amọsa, o si ku akẹkọ kan ni ahamọ awọn ikọ yii.

Image copyright Nigeria airforce
Àkọlé àwòrán Akẹkọ kan si wa lahamọ awọn Boko Haram fun bo se kọ lati gba ẹsin Islam

Ohun ti a gbọ ni wi pe, nitoripe o kọ lati yi ẹsin rẹ pada si Islam gẹgẹbii awọn ikọ naa se n fẹ, ni wọn ko se fi akẹkọ naa silẹ.

Ikilọ awọn ikọ naa ni pe, wọn ko gbọdọ kofiri eyikeyi awọn akẹkọ naa mọ nileewe, lo ku ti n da omi tutu si awọn eeyan lọkan bayii lori ọrọ naa.