Ọsun PDP: Adari tuntun foju han lẹyin wahala ọdun meji

Ami idanimọ PDP Image copyright @OfficialPDPNig
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ oselu PDP yan adari tuntun npinlẹ Ọsun

Lẹyin wahala ati edeaiyede ọdun meji, ẹgbẹ oselu PDP ni ipinlẹ Ọsun ti ni awọn adari tuntun.

Eyi foju han lẹyin eto idibo to waye laarin awọn asoju ẹgbẹ oselu naa kaakiri wọọdu idibo lati yan igbimọ asiwaju tuntun ni ọjọ aiku.

Saaju ni eto idibo si igbimọ asiwaju ẹgbẹ oselu naa lawọn wọọdu ti waye lọjọ abamẹta.

Ju gbogbo rẹ lọ, ko jọ bi ẹnipe alaafia n jọba ninu ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ọsun pẹlu bi o se jẹ wi pe, awọn ọmọlẹyin Sẹnetọ Iyiọla Omisore, to jẹ ọkan gboogi lara awọn asiwaju ẹgbẹ oselu naa, se kọ lati kopa ninu idibo ọhun.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸ wo 'idanilẹkọ' ati ifọrọwanilẹwo ti Ọmọ Ibadan se pẹlu BBC

Lẹyin ti esi idibo naa jade, Ọgbẹni Sọji Adagunodo lo jawe olubori gẹgẹbii alaga tuntun fun ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ọsun, ti ọgbẹni Bọla Ajao si jẹ akọwe ẹgbẹ oselu naa.

Ninu ọrọ akọsọ rẹ, alaga tuntun fun ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ọsun, Sọji Adagunodo ni, ẹgbẹ oselu PDP yoo parapọ lati mu ala awọn ọmọ ẹgbẹ, ati paapaa julọ awọn eeyan ipinlẹ Ọsun sẹ, lasiko idibo sipo gomina to n bọ lọna nipinlẹ naa.

Titi di igba ti a fi n ko iroyin yii jọ, Sẹnetọ Iyiọla Omisore atawọn igun rẹ ninu ẹgbẹ oselu naa, ko tii salaye ni pato, idi ti wọn ko fi kopa ninu idibo ọhun.