Isẹlẹ Dapchi: APC, PDP n sọ'ko ọrọ sira wọn

Lai Mohammed, Minisita fun eto iroyin Image copyright @OfficialPDPNig
Àkọlé àwòrán Ijọba apapọ Naijiria ni o yẹ ki wọn tun iwe asẹ ẹgbẹ oselu PDP gbeyẹwo

Ibeere ti ọpọ onwoye lagbo oselu Naijiria nbeere ni pe, se ẹgbẹ oselu APC fẹ yọwọ kilanko ẹgbẹ oselu PDP lawo oselu Naijiria ni?

Eyi ko si sẹyin ọrọ ti minisita feto iroyin lorilẹede Naijiria, Lai Mohammed, sọ nilu Eko lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lori igbesẹ to waye lati tu awọn akẹkọ Dapchi silẹ.

Nibẹ ni Alhaji Lai Mohammed ti ni oun to buru jọjọ ni pe ẹgbẹ oselu PDP ti ọwọ oselu bọ wahala awọn ọmọ Dapchi naa,

Muhammed ni " Asiko ti to fun atungbeyẹwo ilana fun gbigba iwe asẹ iforukọsilẹ fun awọn ẹgbẹ oselu bii PDP, ti wọn ti fidirẹmi yala gẹgẹ bii ẹgbẹ oselu to n sejọba ni abi eyi to n se atako."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Lai Muhammed tun yannana ọrọ kan, ti aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari sọ, lasiko to fi n gbalejo awọn akẹkọ Dapchi nilu Abuja.

O ni gẹgẹ bii aarẹ Buhari ti wi "ijọba ko ni faye gba ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ to fẹ maa fi oselu se ọrọ aabo lorilẹede yii. Nitorinaa, awọn ileesẹ alaabo ko ni tiju ati fi panpẹ ofin gbe awọn kọlọransi bẹẹ."

Àkọlé àwòrán APC, PDP n tahun si ara wọn lori bi nkan se ri lori ijinigbe ati idapada awọn akẹkọ Dapchi

Amọsa, ẹgbẹ oselu PDP ti fesi si ọrọ yi,i ti wọn si ni, ara ọgbọn ti ẹgbẹ oselu APC n da lo n farahan yii, lọna ati rii daju wi pe, ni dandan, Aarẹ Buhari dije gẹgẹbii oludije alailatako lọdun 2019.

Ẹgbẹ oselu PDP ninu atẹjade kan salaye wi pe, ti a ba ni ka da-a silẹ ka tun un sa, ẹgbẹ oselu APC ti ko ni igbimọ majẹobajẹ, ni ibamu pẹlu ofin ẹgbẹ oselu naa, lẹyin ọdun marun gan an lo yẹ ki wọn gba iwe ẹri lọwọ rẹ.

"A fẹ mu u wa si eti igbọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria wi pe, ọgbọn alumọkọrọyi ni ijọba apapọ, ti ẹgbẹ oselu APC n sakoso rẹ n gbimọran rẹ, lati gbogun ti awọn ẹgbẹ oselu alatako ki wọn si lee yẹna fun oludije wọn, Mohammadu Buhari, lati dije gẹgẹbii oludije ti ko latako."