Idije ere oni‘gba mita: Okagbare ta aseyọri Onyali yọ

Blessing Okagbare-Ighoteghonor Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Igba akọkọ niyi ti elere ije obinrin kan yoo tayọ ami ti Mary Onyali-Omagbemi fi lelẹ lọdun mejilelogun sẹyin

Odu elere ori papa ọmọ naijiria nni, Blessing Okagbare-Ighoteghonor, ti fakọyọ ninu idije ere ije oni igba mita nigba to sa idije naa ni iseju aaya mejilelogun o le belenja mẹrin (22.04seconds) nibi idije 2018 Wes Kittley Invitational to waye nilu Texas, lorilẹede Amẹrika lopin ọsẹ.

Eyi si ni igba akọkọ ti elere ije kan ni ilẹ Afirika yoo tayọ aami isẹju aaya mẹwa o le belenja meje (22.07 secs), ti gbajugbaja elere ije ọmọ Naijiria ni, Mary Onyali-Omagbemi fi lelẹ lọdun 1996, tii se ọdun mejilelogun sẹyin.

Pẹlu ami isẹju aaya tuntun yii, Blessing Okagbare-Ighoteghonor ti di obinrin ti ẹsẹ rẹ ya julọ to ba di ere ori papa lorilẹede Naijiria pẹlu bo se sa idije ọgọrun mita ni isẹju aaya mẹwa o le diẹ (10.79secs) saaju.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Blessing Okagbare yoo si kopa ninu idije ọlọgọrun mita nibi idije 2018 Wes Kittley Invitational in Texas.

Bakanna ni ọmọ Naijiria miran, Fabian Edoki pẹlu yoo kopa ninu idije ilẹ fifo, Long Jump nibẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ere ije onigi (relay) ni Blessing Okagbare-Ighoteghonor yoo ti kopa nibi dije Commonwealth ọdun yii

Blessing Okagbare yoo si kopa ninu idije ọlọgọrun mita nibi idije 2018 Wes Kittley Invitational in Texas.

Bakanna ni ọmọ Naijiria miran, Fabian Edoki pẹlu yoo kopa ninu idije ilẹ fifo, Long Jump nibẹ.

Aseyọri nla ni eyi jẹ fun ajọ elere idaraya Naijiria

Awọn alasẹ ajọ elere papa lorilẹede naijiria ti fi idunnu wọn han lori eyi pẹlu ireti pe iroyin ayọ ni fun orilẹede Naijiria nibayii ti idije ere ori papa ilẹ Afirika n gbaradi lati waye laipẹ nilu Asaba lẹkun aringbungbun guusu orilẹede Naijiria.

Idije ere ije onigi nikan ni Blessing Okagbare-Ighoteghonor yoo ti kopa nibi idije ajọ Commonwealth ti yoo waye losu kẹrin ọdun 2018.