Super Eagles: Ìgbaradì bẹ̀rẹ̀ fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹ̀lú Serbia

Àwọn Super eagles pẹlu awọn olukọ wọn nibudo igbaradi wọn Image copyright @NGSuperEagles
Àkọlé àwòrán Lọ́jọ́ ìsẹ́gun ni Super Eagles àti ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Serbia yóò figagbága

Ikọ̀ Super Eagles ti bẹ̀rẹ̀ ìgbaradì fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́ sọ́rẹ̀ẹ́ kejì ti yóò gbá lọ́jọ́ ìsẹ́gun pẹ̀lú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀èdè Serbia.

Lọ́jọ ẹtì tó kọjá ni Super Eagles fi agba han akẹẹgbẹ́ rẹ̀ láti orílẹ̀èdè Poland pẹ̀lú ayò kan sí òdo níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́ sọ́rẹ̀ẹ́ àkọ́kọ́ tó gbá ní ìgbaradì fún ìdíje ife lyẹ àgbáyé tí yóò wáyé ní osù kẹfà ní orílẹ̀èdè Russia.

Ní ọjọ àbámẹ́ta tó kọjá, ni ikọ̀ Super Eagles gbéra kúrò ni Poland lọ sí ìlú London níbi tí yóò ti kojú ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀èdè Serbia fún ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ̀ẹ́ sọ́rẹ̀ẹ́ lọ́jọ́ ìsẹ́gun.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Títí di ìgbà ti a n sọ ọrọ yii, balogun ikọ naa, Mikel Obi ko tii darapọ mọ awọn akẹgbẹ naa biotilẹ jẹ wi pe ireti wa pe yoo darapọ mọ wọn fun ifẹsẹwọnsẹ naa.