MMM: Àìsàn ọkàn ló pa Mavrodi lẹ́ni ọdún méjìlélọ́gọ́ta

Olùdásílẹ̀ ìlànà sogúndogójì MMM, Sergei Mavrodi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àìmọye mílíọ̀nù ọmọ ilẹ̀ Russian lo pàdánù owó wọn sọ́wọ́ Sergei Mavrodi ní sáà ọdún 1990

Olókoòwò ọmọ ilẹ̀ Russian kan, Sergei Mavrodi, tíí se olùdásílẹ̀ ìlànà sogúndogójì MMM, ti àìmọye mílíọ̀nù ọmọ ilẹ̀ Russian àti Nàìjíríà pàdánù owó wọn sọ́wọ́ rẹ̀ ní sáà ọdún 1990 àti 2017, ti járe láyé láti pasẹ̀ àìsàn ọkàn.

A gbọ́ pe Mavrodi, tíí se ẹni ọ̀dún méjìlélọ́gọ́ta ni wọ́n gbé dìgbà-dìgbà lọ sílé iwòsàn nírọ̀lẹ́ ọjọ́ karùnúndínlọ́gbọ̀n osù kẹta nítorí àyà tó ń roó, àmọ́ tó gbẹ̀mí mì lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tó délé ìwòsàn.

Ìlànà sogúndogójì MMM tí Mavrodi dá sílẹ̀ ni àwọn olùdókówò ti máa ń jẹ èrè ìdá ogún sí ìdá márùndínlagọ̀rin owó tí wọn fi dókòwò láàárín osù kan, tó fi mọ́ owó àjẹmọ́nú mìíràn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPẹtẹsi akọkọ ni Naijiria

Ọ̀pọ̀ oríllèdè lágbàáyé ni wọ́n ti tẹ́wọ́gba ìlànà sogúndogójì MMM yìí, tó fi mọ́ oríllèdè wa Nàìjíríà sùgbọ́n ìjọ̀ba ilẹ̀ wa ti gbẹ́sẹ̀lé ìlànà sogúndogójì MMM yìí, tí owó ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wọ igbó.