Kwara: Agbófiró mu àwọn ajọ́mọgbé méjì

Wọ́n kó bọwọ́bọwọ́ sí ọwọ́ èèyàn kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Alamí ló ta àwọn agbóòfiró lólobó nípa ìwà láabi àwọn amòkùnṣìkà yii

Ọwọ́ àwọn agbóòfiró ti tẹ àwọn èèyàn kan fún ẹ̀sùn ìjínigbépa ńìpínlẹ̀ Kwara.

Alamí lo ta àwọn agbóòfiró lólobó nípa ìwà láabi àwọn amòkùnṣìkà yii.

Awọn afunrasí ọ̀daràn náà, tí wọ́n kéde orúkọ wọn gẹ́gẹ́bíi Kazeem Abdulsalam, ọmọ ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta, tó wá láti ìlú Omù àrán pẹ̀lú Adamu Hussein láti ìlú Ilọrin, lọ́wọ́ àwọn agbófiró àbò-ara-ẹni-làbò-ìlú, Civil defence tẹ̀, ní ibùba ìjínigbépa wọn tó wà ní ìletò Afọn Ọ̀lẹ́yọ̀ ǹípínlẹ̀ Kwara.

Akàrà tú sépo fún àwọn kọ̀lọ̀rànsí náà nígbà tí wọ́n ní kí ọ̀kan lára àwọn oníìbárà wọn, Abdulrahman Mumini ó lọ wá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀rìnlélúgba náírà wá láti fi ṣètùtù, tí onítọ̀ún sí fi ìsẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn ọlọ́ọ̀pá létí.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ àbò-ara-ẹni-làbò-ìlú, Civil defence ńìpínlẹ̀ Kwara, ọ̀gbẹ́ni Ayọ̀délé Bello tó fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ f'áwọn oníròyìn fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ pẹ̀lúu àfikún wí pé áwọn agbóòfiró ǹ ṣiṣẹ́ lóríi ọ̀rọ̀ náà láti ríi wí pé gbogbo àwọn tí aje ọ̀rọ̀ náà bá ṣí mọ́ lórí ni wọn fi pańpẹ́ òfin gbé.