Ighalo: Ìdíje bọ́ọ̀lù ti yàtọ̀ ní China

Odion Ighalo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ighalo ni nǹkan ti yàtọ̀ ní líìgì orílẹ̀èdè China

Agbábọ́ọ̀lù orílẹ̀èdè Nàíjíríà Odion Ighalo ti sọ wí pé ojú àná ni àwọn èeyàn fi ń wo ìdíje eré bọ́ọ̀lù lórílẹ̀èdè China, nítorípé nǹkan ti yàtọ̀ báyìí.

Ighalo ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ní líìgì orílẹ̀èdè China le ju nǹkan tí òun lérò láti bá níbẹ̀ nígbà tí òun ń kúrò ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ síbẹ̀.

Ní ọdún tó kọjá ni Ighalo darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Changchun Yatai ní ilẹ China lẹ́yìn tí wọ́n san ogún mílíọ̀nù pọ́ùn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lóríi rẹ̀.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ighalo ní ìgbé ayé ati oúnjẹ gbogbo ló yàtọ̀ láàárín orílẹ̀èdè China àti Gẹ̀ẹ́sì

Onírúurú àwọn agbábọ́ọ̀lù ni wọ́n ti lọ sí orílẹ̀èdè China láti lọ rèé máa gbá bọ́ọ̀lù jẹun níbẹ̀ ṣùgbọ́n èro ọ̀pọ̀ òǹwòye ni wí pí líìgì orílẹ̀èdè náà kò tíì gbéwọ̀n tó bí ó ti ṣe yẹ lọ.

Orílẹ̀èdè mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ighalo ti gbá bọ́ọ̀lù jẹun báyìí, lẹ́yìn tí ó ti kọ́kọ́ gbà bọ́ọ̀lù lórílẹ̀èdè Nigeria, Norway, Italy, Spain, àti ilẹ Gẹ̀ẹ́sì kí ó tó tún gúnlẹ̀ sí China.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù náà ṣàlàyé wí pé nǹkan yàtọ̀ láàárín orílẹ̀èdè China àti Gẹ̀ẹ́sì, ìgbé ayé wọn, oúnjẹ wọn gbogbo rẹ̀ ló yàtọ̀'

Láti ìgbàtí ó ti tẹkọ̀ létí lọ sí China, ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni Ighalo ti gbá nínuú èyí tí ó ti gbá góòlù mẹ́ẹ̀dógún sínú àwọ̀n.