Sé ẹ̀bẹ̀ PDP jẹ́ ìtẹ̀wọ́gbà bí?

Agboorun, ami idanimọ PDP Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán PDP ní ohun tí ó kọjá ìbò lọ làwọn ń lé

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàíjíríà fún àṣìṣe àtẹ̀yìnwá tó ti se, tó sì ṣèlérí láti mú àyípadà ọ̀tun bá ètò òṣèlú Nàíjíríà, tí wọ́n bá tún fún un ní àǹfààní láti darí orílẹ̀èdè yìí lẹ́ẹ̀kan síi lọ́dún 2019.

Alága àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ òsèlú PDP ní orílẹ̀èdè yìí, Ọmọọba Uche Secondus ní, fún ọdún mẹ́rìndínlógún tó fi se ìjọba, ń ṣe lẹ́gbẹ́ òṣèlú náà já àráàlú kulẹ̀, tó sì jẹ ayé taani yóò mú mi.

Onírúurú awuyewuye ni ọ̀rọ̀ yìí ti wá dá sílẹ̀ pẹ̀lú bí àwọn èèyàn kan ṣe ń sọ wí pé, ẹ̀bẹ̀ wọn ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí àwọn míràn sì sọ pé aṣọ kò bá ọmọ́yẹ mọ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Alága PDP, Uche Secondus ní PDP tọrọ àforíjìn lórí àwọn àṣìṣe rẹ̀ ní fún ọdún mẹ́rìndínlógún tó fi se ìjọba

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú BBC, aṣíwájú àjọ ajàfẹ́ẹ̀tọ́ aráàlú kan, Centre for Human Rights and Social Justice (CHRSJ), ọ̀gbẹ́ni Adéníyì Sulaiman ní ẹ̀bẹ̀ ẹgbẹ̀ òṣèlú PDP kò leè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú àwọn ọmọ Nàíjíríà nítorí ọ̀pọ̀ aṣemáṣe wọn.

"Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tàpá sí ìwé òfin ilẹ̀ẹwa lọ́pọ̀ ìgbà nítorí wọ́n nígbàgbọ́ pé àwọn ní Ọbásanjọ́, Àtíkù àti àjọ elétò ìdìbò níìgbẹ́jọ́ láti ṣe màdàrú ìbò.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Wọ́n jí owó wa, bákan náà ni APC ń ṣe báyìí. Tí ó bá yá àwọn náà á wá máa tọrọ àforíjò."

Ó ní ẹgbẹ́ òṣèlú tí púpọ̀ àwọn aṣíwájú rẹ̀ ní ẹjọ́ níwájú àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ lórílẹ̀èdè Nàíjíríà kò tíì ṣetán fún àforíjì.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán APC ti sọ pé kò tíì jọ bí ẹnipé PDP ti túúba délẹ̀ lóòótọ́

"Wọn kò ní ìfẹ́ Nàíjíríà tàbí àwọn ọmọ Nàíjíríà. A kò nílò Nàíjíríà wọn, kí wọ́n lọ bọ̀wọ̀ fún òfin kí wọ́n sì dá gbogbo owó tí wọ́n ti kó ní àṣùwọ̀n ìjọba padà ní gbangba."

Ẹ̀bẹ̀ PDP kìí ṣe arúmọjẹ láti tan aráàlú fún ìbò lọ́dún 2019

Àmọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ohun tí àwọn ń lé kọjá ìbò lọ bí kòṣe láti kọ́kọ́ ṣe àtúnṣe ẹgbẹ́ náà fún ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun eléyí tí yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú àfojúsùn àwọn ọmọ Nàíjíríà.

Olórí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn gúúsù Nàíjíríà, Ọ̀mọ̀wé Eddie Ọláfẹ̀sọ̀ ṣàlàyé fún BBC pé ẹ̀bẹ̀ awọn kìí ṣe arúmọjẹ láti tan aráàlú fún ìbò lọ́dún 2019.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán PDP wí pé ẹ̀bẹ̀ awọn kìí ṣe arúmọjẹ láti tan aráàlú fún ìbò lọ́dún 2019

"Ó dá mi lójú pé àwọn ọmọ Nàíjíríà yóò tẹ́wọ́gba ẹ̀bẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú wa nítorí wọ́n mọ̀ pé kò sí arúmọjẹ nínúu ẹ̀bẹ̀ wa."

APC ti sọ pé kò tíì jọ bí ẹnipé PDP ti túúba délẹ̀ lóòótọ́

Níbáyìí, ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣèjọba lórílẹ̀èdè Nàíjíríà, APC ti sọ pé kò tíì jọ bí ẹnipé PDP ti túúba délẹ̀ lóòótọ́.

Nínú àtẹ̀ád kan tí adarí ìpolongo rẹ̀, Bọ́lájí Abdullahi fọwọ́sí ṣe làá kalẹ̀, 'ẹgbẹ́ òṣèlú PDP yóò ní láti jẹ́wọ́ àìṣedédé rẹ̀ gbogbo nítorí àwọn ọmọ Nàíjíríà ṣì ń kérora ìṣòro tí wọ́n dá sílẹ̀.'