Èkó: Ọ̀bọ lé àwọn ènìyàn kúrò ní Gbàgádà

Aworan obo lori igi
Àkọlé àwòrán,

Àwọn ènìyàn sọ wípé àwọn ọ̀bọ náà dá ouńjẹ tí wọ́n fi májèlé sí nínú mọ̀ nítorí wọn kò ní jẹ ẹ́

Àwọn ọ̀bọ àti ìnàkí ti lé àwọn ènìyàn kúrò lágbèègbèe Soluyi/ - Sosanya ní Gbàgádà ní ìlú Èkó.

Alága àwọn onílé ní agbèègbè náà, Adigun Olaleye sọ fún ilé-isẹ́ ìròyìn tí ìjọba orílẹ̀èdé Nàíjíríà, NAN wípé àwọn kò mọ ohun tí àwọn yóò se nípa àwọn ọ̀bọ náà mọ́.

Adigun ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọ̀bọ náà ma ń lé àwọn ènìyàn kúrò ní ilé wọn, nígbàtí àwọn elòmíràn máa ń farapa tí wọ́n bá ń wá ọ̀nà láti kojú àwọn ọ̀bọ tó wọ ilé wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Alága àwọn onílé náà wá pàrọwà sí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó àti ìjọba àpapọ̀ láti wá rànwọ́nlọ́wọ́ láti kojú àwọn ọ̀bọ náà, nítorí àwọn eranko náà ti jẹ oúnjẹ wọn, àtiwípé wọ́n ti ba dúkìá wọn jẹ́.