Ìlú Borno: Ènìyàn 14 kú ní ibùgbé ogúnléndé tó gbaná

Maapu ibi isele naa
Àkọlé àwòrán,

Láìpé yí ni Boko Haram se ìkọlù sí ibùgbé àwọn ogúnléndé náà tí wọ́n sì pa ènìyàn moọ́kànlá pẹ̀lu àwọn òsìsẹ́ Àjọ Àgbáyé (UN) mẹ́ta

Ó kéré tán ènìyàn mẹ́rìnlá ti pàdánù ẹ̀mí wọn nígbàtí ogúnlọ́gọ̀ sì parapa nínú ìjàmbá iná tó wáyé ní ibùgbé àwọn ogúnléndé tó wà ní agbègbè Rann, ní ibodè Nàìjíríà àti Cameroon lẹ́kun Ìlà-Oòrùn Àríwà orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Àwọn òsìsẹ́ àjọ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Borno sọwípé iná náà bẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀ Ojo Aje, nígbàtí afẹ́fẹ́ fẹ́ iná tí àwọn ènìyàn dá láti fi se ouńjẹ, tó sì jó fún wákàtí mẹ́ta kó tó di wípé wọ́n rí iná náà pa.

Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé wà nínú àwọn tó farapa nínú ìsẹ̀lẹ̀ náà, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì wà ní ilé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ìsẹ̀lẹ̀ yí wáyé láì tíì pé osù kan ti àwọn ẹsinòkọkú Boko Haram se ìkọlù sí ibùgbé àwọn ogúnléndé náà tí wọ́n sì pa ènìyàn moọ́kànlá pẹ̀lu àwọn òsìsẹ́ Àjọ Àgbáyé (UN) mẹ́ta.