Ìlú Eko: Ààrẹ Buhari yóò sàbẹ̀wò , àwọn òsìsẹ́ gba ìsinmi l’Ọ́jọ́bọ̀

Aarẹ Muhammadu Buhari, Oloye Bisi Akande Akande ati Asiwaju Bọla Tinubu n sọrọ
Àkọlé àwòrán,

Ipade laarin Tinubu, Akande ati Buhari ti fa oniruuru awuyewuye lẹsẹ

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, Osù Kẹẹ̀ta gẹ́gẹ́bí ọjọ́ Ìsinmi fún àwọn òsísẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

Kọmísọ́nà fún ọ̀rọ̀ ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Eko, Kehinde Bamigbetan nínú àtẹ̀jáde fún àwọn oníròyìn sọwípé àbẹ̀wò Ààrẹ Muhammadu Buhari fún ní Ọ́jọ́bọ̀ àti Ẹtì ọ̀sẹ̀ yii sí ìpínlẹ̀ náà, ló jẹ́ kí wọ́n fún àwọn ènìyàn ní ìsinmi ọjọ́ kan náà.

Bamigbetan ní èyí yóò fún àwọn òsísẹ́ ní ànfààní láti jáde lọ́gọ̀ọ̀rọ̀ láti pàdé Ààrẹ Buhari tí yóò se àgbékalẹ̀ àwọn isẹ́ tó làmìlàaka ní ìpínlẹ̀ náà.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: