Koko iroyin: Àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí Eko, ìjàmbá iná Borno
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
Ààrẹ Buhari yóò sàbẹ̀wò sí ìlú Eko
Oríṣun àwòrán, @NGRPresident
Ipade laarin Tinubu, Akande ati Buhari ti fa oniruuru awuyewuye lẹsẹ
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, Osù Kẹẹ̀ta gẹ́gẹ́bí ọjọ́ Ìsinmi fún àwọn òsísẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà.
Kọmísọ́nà fún ọ̀rọ̀ ìròyìn ní ìpínlẹ̀ Eko, Kehinde Bamigbetan nínú àtẹ̀jáde fún àwọn oníròyìn sọwípé àbẹ̀wò Ààrẹ Muhammadu Buhari fún ní Ọ́jọ́bọ̀ àti Ẹtì ọ̀sẹ̀ yii sí ìpínlẹ̀ náà, ló jẹ́ kí wọ́n fún àwọn ènìyàn ní ìsinmi ọjọ́ kan náà.
Ènìyàn 14 kú ní ibùgbé ogúnléndé tó gbaná ní Borno
Ó kéré tán ènìyàn mẹ́rìnlá ti pàdánù ẹ̀mí wọn nígbàtí ogúnlọ́gọ̀ sì parapa nínú ìjàmbá iná tó wáyé ní ibùgbé àwọn ogúnléndé tó wà ní agbègbè Rann, ní ibodè Nàìjíríà àti Cameroon lẹ́kun Ìlà-Oòrùn Àríwà orílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé wà nínú àwọn tó farapa nínú ìsẹ̀lẹ̀ náà, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì wà ní ilé ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú. Ẹka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní bíí
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn ọmọ Yorùbá àtàtà lẹ́nu wò nípa bí wọ̀n se gbọ́ òwe sí.
Àwọn ọmọ Yorùbá àtàtà: Báwo lẹ se gbọ́ òwe sí ?