Ìgbẹ́tì: Òkè Ìyámàpó ló gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ogun

Ìlú Ìgbẹ́tì jẹ́ ọ̀kan lára ìlú tó wà ní agbègbè Òkè Ògùn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Òkè ló yí ìlú Ìgbẹ́tì po. Orí òké Ìyámàpó ni wọ́n ti sọ Ìlú Ìgbẹ́tì kalẹ̀.

Ìgbẹ́tì ni ìlú tí a gbà tì, tí a kò rí gbà lásìkò ogun, èyítí í se ìlú Àgbàtì àmọ́ tó wá di Ìgbẹ́tì báyìí.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Oke mẹrindinlogun lo wa nilu Igbẹti ni Oke Ogun nipinlẹ Oyo, ṣugbọn Oke Iyamopo lo tobi ju.

Iyamọpo ni akinkanju obinrin to gba awọn eniyan Oyo silẹ lọwọ ogun fulani nigba naa.

BBC Yoruba n parọwa pé ki a jẹ ki awọn ewe iwoyi mọ sii nipa itan ati awọn ohun ajogunba ilẹ Yoruba.

Awọn ìlú ilẹ̀ Yoruba kun fun itan ati ẹkọ loriṣiirisi.