‘Ìgbìmọ̀ kan ni yóò sàyẹ̀wò sáà olóyè APC’
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bọ́lájí Abdullahi: Ìgbìmọ̀ kan ni yóò sàyẹ̀wò sáà olóyè APC

Akọ̀wé ìpolongo fún ẹgbẹ́ APC, Alhaji Bọ́lájí Abdullahi ní ẹgbẹ́ ti gbe ìgbimọ̀ kan kalẹ̀ fún àyẹ̀wò sáà àwọn olóyè ẹgbẹ́ APC.

Lásìkò tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, Abdulahhi ní ààrẹ gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ pé kó tako àfikún sáà àwọn olóyè ẹgbẹ́ APC náà.

Ó ní ìkùnsínú kò níí se aláìwá nínú ẹgbẹ́ APC, bóyá wọ́n se àfikún sáà àwọn olóyè ẹgbẹ́ náà àbí wọ́n se ètò ìdìbò tuntun.

Abdullahi sọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń fèsì lórí ọ̀rọ̀ tí ààrẹ Buhari sọ pe àfikún sáà àwọn olóyè ẹgbẹ́ APC, tí wọ́n se láìpẹ́ kò bófinmu.