Ethiopia: Abiy Ahmed di olóòtú ìjọba

Abiy Ahmed
Àkọlé àwòrán,

Olori agbarijọpọ ẹgbẹ to wa nijọba lo ma'n saba je olotu ijọba ni Ethiopia

Agbarijopo ẹgbẹ to wa nijọba lorilẹẹde Ethiopia, EPRDF, ti yan Abiy Ahmed gẹgẹ bi olori wọn tuntun.

Losu keji ọdun yii ni Hailemariam Desalegn s'adede fipo silẹ gẹgẹ bi olotu ijọba.

Ọmọ ẹya Oromo nii se, eleyi to jẹ ẹya to wa nidi iwọde ifẹhonu alatako ijọba fun ọdun mẹta sẹyin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Abiy ni yoo je olotu ijọba akọkọ ọmọ ẹya Oromo lati ọdun mẹtadinlọgbọn ti EPRDF ti wa ni ijọba.

Ifiposilẹ Desalegn sokunfa ikede ilu o fara rọ ni Ethiopia

Iyansipo ọgbeni Abiy tunmọ si pe ohun ni yoo bọ si ipo olootu ijọba lẹyin Hailemariam Desalegn to s'adede fipo silẹ losu to kọja.

Ifiposilẹ ọgbẹni Desalegn sokunfa bi ijọba ti se kede ilu ofara rọ jakejado orilẹẹde naa.