Ìgbaradì Super Eagles: Ayò méjì ni Serbia fi sàgbà

Aworan Super Eagles Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Epa o boro fun asole Naijiria Francis Uzoho pelu bi Serbia se je ami ayo meji sodo

Serbia ti fidi iko ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles remi pelu ayo meji sodo.

Eyi ni igba ẹlẹkeji ti Super Eagles yoo padanu ifẹsẹwọnsẹ kankan labe oludari Gerhnot Rohr.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti'n fi ero ọkan wọn han lori abajade ifẹsẹwọnsẹ naa

T'oun ti bi wọn ti se fẹyin ikọ Super Eagles gbole, awọn ọmọ Naijiria kan, to fi mo gbajugbaja DJ, DJ Cuppy fife han si orilẹẹde wọn.

Spain fiya je Argentina

Ẹwẹ, ikọ Argentina to wa ninu isọri kanna pẹlu Super Eagles ninu idije ife ẹyẹ agbaye,World Cup, to'n bo lọna je iyan wọn nisu nigba ti wọn koju Spain.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Isco je ami ayo mẹta ninu ifẹsẹwọnsẹ naa

Ami ayo mẹfa s'ọkan ni wọn gba ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Isco je ami ayo mẹta ninu ifẹsẹwọnsẹ naa ti Spain fi gbogbo ọna sagba Argentina.

Lionel Messi to jẹ Balogun ikọ naa ko kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ naa nitori pe o farapa.

Pẹlu aseyori yii, o ti di ifẹsẹwọnsẹ mejidinlogun ti Spain ti gba lai si ijakulẹ lati igba ti Julen Lopetegui ti gba akoso ikọ naa lẹyin ti wọn ja wọn ninu idije Euro 2016.

Abajade ifẹsẹwọnsẹ miran

Russia 1-3 France

Switzerland 6-0 Panama

Germany 0-Brazil

Tanzania 2-0 DR Congo