Oluwo: Èmi ni atọ́nà oyè Wàzírì nílẹ̀ Yorùbá

Oluwo tilu Iwo
Àkọlé àwòrán Oluwo tilu Iwo so pe oun fẹ di Ọba onilawani (Emir) ilẹ Yoruba

Ọ́ba Rasheed Adewale Akanbi, Oluwo tilu Iwo ti fẹ se ohun ti ẹnikan ko se ri nilẹ Yoruba.

Lọjọ Satide, ọjọ kọkanlẹlọgbọn osu kẹta ọdun yi, Oba alade naa fe gbe igbese manigbagbe, eyi to see se ki o gbegidina isọkan laarin awọn Musulumi ile Yoruba .

O fe funra ara re nikan we lawani fun Waziri akọkọ fun gbogbo ilẹ Yoruba.

Sugbọn igbese naa ti mu ariwisi ọtọọto wa, paapa julo, lati ọdọ awọn onimo ẹsin Islam ni ilẹ Yoruba.

Imaamu kan ni ikọja aaye ni igbesẹ naa

Nigba to n fesi lori ọrọ yii,, Imam Fuad Adeyemi, to je Imam agba fun ẹgbẹ Al-Habibiyah jake jado orilẹẹde Naijiria, to si tun je asoju iwọ oorun guusu ilẹ Yoruba labe ajọ to n seto alalaji lorilẹẹde Naijiria, (NAHCON) ni, looto ni ilu Iwo jẹ ilu to lami laaka nipa ẹsin Islam sugbọn o koja agbara Oluwo lati yan Waziri fun gbogbo ile Yoruba.

Ẹ gbọ oun ti wọn sọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionImam Fuad tako Oluwo lori wiwe lawani

Sugbọn ko jọ bi pe Oba Rasheed setan lati gbọ arọwa kankan paapa julọ lati ọdọ awọn Imamu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOluwo fe fi oye Waziri lọle nilẹ Yoruba

Imaamu mii naa ni ẹkọ gbigbona nfẹ suuru

Imam Abdulsalam Olayiwola to je Imam masalasi Radio Kwara ni ilu Ilorin so pe iru ọrọ bayi gba suru.

Fun Oluwo ati awọn Oba Ile Yoruba, o ni o se pataki lati ni ifikunlukun lori iru igbese yi fun alafia ati isọkan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionImam Abdulsalam Olayiwola

Oye Waziri, gẹgẹ bi ohun ti awọn onimọ so, jẹ oye ''Olubadamọran.''

Ni ilẹ Yoruba lapapọ, ko si ẹnikan to je oye yi, sugbọn ni ilu Ilorin, akọsile wa pe, Oloye Olusola Saraki to ti di oloogbe jẹ oye naa, eleyi ti Oba Ilu Ilorin nigbakanri, Oba Zulu Gambari, fi daa lọla.