Ọjà Mákòkó : Ibẹ̀ ni ọba ẹja wa ní Èkó

Ọjà Mákòkó : Ibẹ̀ ni ọba ẹja wa ní Èkó

Wọ́n ní àìrìn jìnnà ni àìrì abuke ọ̀kẹ́rẹ́, ẹnu kò gba ìròyìn nígbàtí BBC Yorùbá kàn sí gbajúgbajà ọjà ẹja tó wà ní Mákòókó ní Èkó, a sì ríi pé ẹnití kò bá tíì dé ibẹ̀ ra ẹja, kò tíì jẹ ọba ẹja.

Àwọn ẹja tí orí wọn tó èèyàn ló wà níbẹ̀ bíi ẹja Ọsàn, Ọ̀bọ̀kún, Àbùrúkù, Òwèrè, Àdàsa, Bìràkúsà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Bákannáà ni onírúurú Edé, Akàn àti ọ̀pọ̀ ohun abẹ̀mí míràn tó wà lábẹ́ omi kún ọjà Mákókó.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: