Ikú Deji Falae: Adájọ́ ní kí iléesẹ́ ọkọ̀ òfurufú san 246m

Aworan ọkọ ofurufu to jabọ
Àkọlé àwòrán,

Eniyan mẹtadinlọgbọn lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ofurufu naa to sẹlẹ lọdun 2013

Owo fun ni, ko t'eniyan sugbọn fun ẹbi Deji Falae, to padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ ofurufu ileese Associated Airline lọdun 2013, idẹra diẹ yoo de.

Ọrọ naa ko sẹyin bi Ile ẹjo giga kan nipinle Eko ti se pasẹ pe ki ileesẹ ọkọ ofurufu Associated Airline san owo itanran òjìlérúgba lé mẹfa miliọnu naira fun iyawo rẹ, Ese.

Deji, to jẹ kọmisọna fọrọ asa ati igbafẹ nigba kan ri nipinlẹ Ondo, padanu ẹmi rẹ nigba ti ọkọ ofurufu to n gbe oku gomina tẹlẹri nipinle naa, Olusẹgun Agagu jabọ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed l'eko.

Àkọlé àwòrán,

Deji ati iyawo Ese nigba to si wa laye

Adajọ Hadizat Shagari ni, iyawo Deji ,Ese, fidi ẹjo rẹ mulẹ pẹlu ẹsun to fi kan ileesẹ ọkọ ofurufu Assocaited Airline, to jẹ olujejọ akọkọ ati ajọ to n risi ọrọ ofurufu l'orilẹẹde Naijiria,NCAA.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adajọ sọ pe, lootọ ni ileesẹ naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, ki wọn si lọ san owo itanran fun Ese ati awọn ọmọ rẹ.